Ijoba apapo ti da giwa fasiti FUTA ati FUNAAB duro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Ijoba apapo ti da giwa fasiti FUTA ati FUNAAB duro

Ojogbon Oyewole ati Ojogbon Daramola
Lojobo Tosde ose to koja yi ni atejade kan jade lati odo ijoba apapo, iyen lodo ajo to n ri soro eko nileewe giga, ti Mallam Adamu Adamu je oga agba e, wipe oun da awon giwa agba ileeko fasiti Federal University of Technology, FUTA, Ojogbon Adebiyi Daramola ati Ojogbon Olusola Oyewole ti Federal University of Agriculture, Abeokuta, FUNAAB duro.

Bo tile je pe ohun ti agbenuso ile eko Fasiti FUNAAB so ninu atejade to fi sita fawon akoroyin ni pe, awon ko tii le so boya looto niroyin naa, nitori pe awon ti bere igbese lati sewadi boya looto niroyin naa.
Sugbon ninu atejade ti Dokita Hussaini Adamu, to je akowe agba fidihe ni ileese to n ri si eto eko lorileede yi, iyen Federal Ministry of Education fowo si lo ti so pe ijoba apapo dawon eeyan naa duro latari ejo ti won n je lowo nile ejo pelu ajo to n ri si sise owo ilu mokumoku, iyen ajo EFCC.
Ninu e ni won ti so pe kawon oga agba mejeeji naa ko gbogbo eru to wa nikawo won fawon to tun je gege bi oga lawon ileeko naa, ki ise si maa lo bo se n lo.
AWIKONKO gbo pe, bawon osise atawon akekoo ile eko FUTA se gbo iroyin yi, ilu ni won lo o gbe, ti won sib ere sii korin kaakiri inu ogba wipe awon ti reyin ota won, ti ko je kawon gbadun latigba ti won ti gbe de be.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI