Eyi lawon igbimo TAMPAN fun isinku Pasito Ajidara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Eyi lawon igbimo TAMPAN fun isinku Pasito Ajidara

Bi ipalemo isinku agba osere nni, Oloogbe Omoba Samuel Adesina Adesanya, Pasito Ajidara ti n sunmo etile, iyen ayeye ti yoo bere l'Ojoru Wesde ose to m bo, ojo kerinlelogun osu yii, Egbe osere Theater and Arts Practitioner Association of Nigeria, TAMPAN ti gbe oruko awon igbimo ti yoo sagbeteru ayeye isinku Gomina won sita fawon eeyan lati mo awon ti won yoo pe bi won ba fee bere ohunkohun nipa bi eto isinku yoo se lo.

Ninu atejade ti okan lara awon omo egbe naa, Ogbeni Olusegun Agbaakin Akinwunmi fi sori ero ayelujara laipe yi lo ti safihan awon merinla naa, pelu awon meji miran, to fi je merindinlogun.

Awon merinla naa ni;
Otunba Bolaji Amusan, Mista Latin – Alaga
Simon Oguntola – akowe
Segun Adesegun - Akapo
Isiaka Ogunnumesi
Yemi Adegunju
Adeleke Adetutu, Seyi Crown
Yinka Adebanjo
Alaaji Lateef Dehinde
Owolabi Ajasa
Olaleye Nathaniel
Baruwa Emmanuel
Bola Odunuga
Folasade Oludele
Yomi Fash-Lanso

Awon meji miran lori eto iroyin ni;
Gbenga Edun ati
Solaja Oluwafemi

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI