Ile ejo ti da Alagba Solomon Alao duro gege bi Olori ijo C&S lagbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Ile ejo ti da Alagba Solomon Alao duro gege bi Olori ijo C&S lagbaye

Ijo Sacred Cherubim and Seraphim ti kede pe Ile ejo giga kan to fikale silu Eko laipe yi ti da Alagba Solomon Alao duro gege bi Olori ijo naa lagbaye.

Won si tun pase pe ki o ye pe ara e ni Baba Aladura olori ijo naa mo nitori o n tabuku ba ijo naa pelu awon igbese to n gbe, eyi to lodi sofin ati ilana ti won fi da ijo naa sile.

Ase yi waye leyin ti awon agbaagba ninu ijo naa pe Alagba Solomon Alao lejo pe awon igbese to n gbe ninu ijo naa lodi si ofin to gbe ijo naa duro lorileede naijiria ati kaakiri agbaye.

Ojo ketalelogun osu to koja ni Adajo to da ejo naa, iyen Onidajo Lawal Akapo so pe ki Alagba Alao ko gbogbo awon eru ijo Kerubu ati Serafu to wa lowo ni kiakia.

Akapo wa yan Baba Aladura, Alagba Adebayo Abiola lati tesiwaju gege bi Olori ijo naa, ko si maa sakoso ijo naa pelu liana.

AWIKONKO gbo pe ojo kejila osu kesan ni won gbe Alagba Alao pelu awon agbaagba kan bii Alagba David Salako ati akowe ijo naa Alagba Akin Owolabi lo sile ejo nigba ti won so pe awon gan an ni igi leyin ogba fun Alagba Alao, nitori awon gan an ni won gba ona eru lati yan an sipo gege bi Olori ijo naa, ti won ko so je kawon agbaagba kan ninu ijo naa mo si.

Won ni yato si wipe won yan Alagba Alao, ona ti won gba lati yan an lodi sofin ati ilana ti won fi n yan Olori ninu ijo Kerubu ati Serafu.

Nigba to n da ejo naa, Onidajo Lawal Akapo so pe oun da Alagba Alao duro, ki o si yee farahan mo gege bi Olori ijo naa atipe ki o ye pe ara e ni nnkan ti ko je, iyen gege bi olori ijo naa.

Akapo so pe lawon ipade tabi ibi ijosin ti won ba pe e si gege bi
olori ijo Kerubu ati Serafu, ko gbodo lo, ko si so fun won pe oun ko ye ni eni ti won le pe ni olori ijo naa.

Adajo naa wa pase pe ki Alagba Adebayo Abiola tesiwaju lati maa sakoso ijo naa titi di igba ti asiko re yoo fi pe, iyen odun mejo ti won ni so pe won maa n lo lati je Olori ijo naa.

Bakanna lo tun pase pe ki Alagba David Salako gbe opa akoso ijo to wa nikawo e sile fawon agbaagba ninu ijo naa.

Siwaju si ni won tun so pe ko si nnkan to n je ijo Sacred Cherubim & Seraphim Church of Nigeria and Overseas eyi ti won ni Alagba Alao so pe oun je Olori fun, won ni oruko naa ko han si ijo naa lagbaye, bi ko se pe awon kan ni won mo nipa oruko naa.

Lati le fidi oro naa mule lo je ki IROYIN OWURO ba lara awon to sunmo Alagba Alao soro lojo Eti Fraide ose to koja, sugbon oun ti won so ni pe awon ko tii le so ohunkohun bayii ayafi ti Baba Aladura, iyen Alagba Alao ba de lati ilu London to lo lose yii.

Won je ko ye wa pe ose yi, leyin ti Baba Aladura ba de lawon yoo to mo igbese tawon yoo gbe yala lati pe ejo kotemilorun tabi soro fawon oniroyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI