Awon ara oja Sapon yari mo Amosun lowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Awon ara oja Sapon yari mo Amosun lowo

Won lojusaaaju lo fi pin soobu fun won

Laaro Ojobo Tosde ose koja lawon ara oja Sapon nijoba ibile Abeokuta South so pe awon ko nii gba, ayafi ki Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun se atunse lori ona ti won fi pin awon soobu ti won sese ko, eyi ti won so pe won pin fawon.

Gomina Amosun
Gege bi ohun ti a gbo ni pe, won ti fi oro oselu sinu bi won se pin awon soobu naa fawon nitori pe opo awon ti won ko mo bi oro soobu naa se bere ni won wa yoju lati so pe awon naa fee gba ninu soobu naa, to si je pe ilana ti wa nile tele.

Nigba ti awon ara oja naa n bakoroyin wa soro, won so pe l’Ojobo Tosde ose to koja ni Gomina Amosun wa pe awon oruko awon ti yoo lo soobu naa, sugbon iyalenu lo je pe nigba ti won maa pada wa le oruko naa mo ara patako, ayederu iwe ti Gomina fi pe oruko ni won wa le.

Won ni opo awon eeyan ti won ko mo ri rara ni won fun lawon soobu to ye ko je tawon to ti n taja ni oja Sapon tele, iyen awon tijoba wo soobu won. Bee ni won so pe awon osise ijoba ni won lo gbe wa pe ki won wa maa lo soobu naa.

Iyaloja Sapon, Daikoni Olajumoke Abioye nigba to n soro pelu iporuru okan, o so pe oro naa su oun nitori pe gbogbo awon tawon tun le pe ni olori ninu oja Sapon ni won ko ri soobu gba, to je wipe se ni won so fun won pe ki won lo wa ibomiran ti won fee lo, tabi ki won lo sun sile.

Iya agba naa so pe nigba toun gbo soro naa, nise lo re oun wa nitori pe gbogbo awon to ti n lo soobu naa latodun to ti pe ni won ko ri soobu gba, atipe iyalenu lo je foun nigba ti won wa le iwe oruko ti gomina Amosun pe lose to koja, to si je oruko awon eeyan marun ni won yo kuro ninu iwe naa, to je pe oruko awon kan ti won so pe osise ijoba ni won, ni on fi ropo oruko awon eeyan naa.

O ni oun mo pe Gomina Amosun ko mo si nnkan to n sele naa bi ko se pe awon ti ijoba ran ni won wa lati se awuruju naa. O so pe Soobu keji, iyen nomba 2 to je pe Babaloja lo ye ki won fun, atipe Gomina ti pe oruko e gege bi eni ti yoo lo soobu, naa, ko seni to le so bi oro naa se je, to fi je pe oto leni ti won tun fun.

Iyaloja naa wa rawo ebe si Amosun pe ko tete wa se atunse lori oro soobu naa, ko too da wahala tawon ko lero sile laarin ilu. O ni awon ko le la oju awon sile ko je pe awon ti won ko bawon jiya ni won maa wa je igbadun tawon fi odindi odun mefa gbako jiya e.

Babaloja naa, Oloye Femi Akingbade nigba to n soro so pe “Ko si igbese kankan ti a fee gbe, nitoripe Gomina Amosun ti so pe gbogbo eni toun wo soobu loun maa fun ni soobu e pada leyin ti won ba pari, a wa n be Gomina wa pe ko ko fun wan i soobu gege bi a se wa nibe tele. Nomba akoko ni mow a tele, nomba ketalelogbon ni won lo fimi si loke. Kii se emi nikan, a po bee, leyi ti ko si bojumu to.”

Bakanna lo tun so pe won tun gbe soobu kan ti ko to eni kan soso lo, ni won tun gbe feeyan meji ti won ni ki won jo pin. O ni awon tawon ko mo ri ti won so pe osise ijoba ni won, ni won won tun pin soobu to to sawon fun. O lawon tawon wan i oja Sapon mo ara won.
O ni awon ti ranse si Gomina Amosun, sugbon boya ohun awon de odo e tabi ko debe, awon ko le so, sugbon nnkan tawon fee se nipe ko seni ti yoo lo okan ninu awon soobu naa ninu awon ti won pin fun, ayafi ti Gomina Amosun ba wa se atunse le e lori.

Ogbeni Olatunji to je Agbenuso oja Sapon nigba toun naa n fibinu soro so pe odun marun ataabo lawon fi wa ninu ojo ati oorun latigba ti Gomina ti pase pe ki won wo soobu awon, ti won si seleri pe ki won to fun enikeni ni soobu, awon ti won wo soobu won ni won maa koko je igbadun soobu naa.

O ni nigba tawon lo lati lo sewadi lodo Komisana foro ise, awon ko ri fun bii wakati marun tawon fi wan i ofiisi e, sugbon akowe e lawon ri, nnkan to so nipe ijoba yoo gbe igbese le lori, sugbon titi di asiko yii, awon ko tii gbo nnkan latodo ijoba ipinle Ogun.

Okan lara awon oloja, iyen Arabinrin Bangbelu to ba akoroyin wa soro laaro ojo naa so pe ileri ti Gomina Amosun se fawon nigba ti won wa wo soobu awon ni pe kawon farabale nitori pe nomba tawon wa tele lawon maa gba pada, to si je pe bee ni Gomina se pe oruko nigba ti won wa lose to koja, sugbon iyalenu lo je pe kii se bi Gomina Amosun se pe oruko ni o se wa ninu iwe oruko ti won pada wa le.

O lawon mo pe Gomina Amosun ko le lowo si awon iwa ti ko bojumu naa, sugbon awon ti Gomina ran nise ni won n je isekise, sugbon sibe sibe, awon ko ni gba ki won gba satide lowo awon, ki won wag be sande le awon lowo, eto awon lawon n ja fun.
Gbogbo igbese lati ba Komisana foro ise nipinle Ogun soro lo ja si pabo titi di bi a ti n koroyin yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI