Ile eko Fasiti FUTA ti yan giwa tuntun o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 20, 2017

Ile eko Fasiti FUTA ti yan giwa tuntun o

Ojogbon Daramola
Ile eko giga fasiti tijoba apapo nilu Akure, Federal University of Technology ti yan giwa agba tuntun ti yoo tesiwaju nibi ti giwa tele Ojogbo Adebiyi Daramola ba ise de.
 
Bi e o ba gbagbe, ko tii pe ose meji ti ijoba apapo da Ojogbon Daramola duro latari esun ikowoje ti ajo EFCC fi kan an, ti oro naa si w anile ejo titi di asiko yi.

Ojogbon Joseph Adeola Fuwape ni won ti wa fase naa le lowo bayii gege bi giwa keje nile eko naa.

Ninu atejade ti Ogbeni Adegbenro Adebanjo to je olori eto iroyin ati alabojuto bi nnkan se n lo si nileeko naa fowo si nibi ipade ti alaga igbimo isakoso ileeko naa, Senato Joseph Waku dari e l’Ojobo Tosde to koja yi lo ti so pe ki Ojogbon bere ise ni pereu lati Ojoru Wesde, ojo kerinlelogun to m bo yi leyin ti isakoso Ojogbon Daramola ba ti pari lojo Isegun Tusde, ojo ketalelogun osu yi.

Bakanna ni won so pe saa kan soso pere to je odun marun ni Ojogbon Adegbenro yoo lo gege bi giwa ile eko naa

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI