Baba aadota to ji foonu ti foju bale ejo o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 20, 2017

Baba aadota to ji foonu ti foju bale ejo o

Bo tile je pe ojo Aje Monde to m bo yi, iyen ojokejilelogun ni adajo ile ejo Majisireeti to fikale sagbegbe Surulere nipinle Eko, Ogbeni A.A Paul so pe oun yoo tesiwaju ninu esun ti won fi kan Ogbeni Muritala Olaniyan, eni aadotan odun.
 
Esun ti won fi kan Ogbeni Olaniyan ni pe o ji foonu onibara e kan, Ogbeni Godwin Enoch ladugbo nigba to lo ogbon alumokoroyi lati fi ji foonu naa lojo kejila osu yi ni nnkan bi aago mesan aaro ojo naa.

Inu soobu ni won so pe Olaniyan ti loo ba Enoch to si so pe oun fe nnkan, nibi ti won ni Enoch ti wa n nnkan ti Olaniyan fee ra, ni o ti nawo mu foonu naa, to si tete fibe sile.

Ko tii ju iseju meedogun ti Olaniyan kuro ni soobu Enoch lo bere sii wa foonu e, to si lo ba Olaniyan nile pe foonu oun to mu loun wa gba, sugbon se ni won so pe Olaniyan yari kanle pe oun ko loun mu.

Loju ese ni Enoch ti gba tesan olopaa lo lati lo fejo sun, ti won si wa gbe nile lati lo foro wa lenu wok o too dipe o jewo leyin bii wakati meta. Nibe lawon olopaa ti so pe a fi kawon foju e bale ejo.

Nigba to n soro, agbejoro olopaa, Ogbeni Christopher Okoliko to so niwaju ile ejo pe foonu ti Olaniyan ji je egberun mejidinlogun, tawon si ti gba foonu naa lowo e. O so pe iwa ti olaniyan hu yi lodi si ofin ole jija ninu iwe ofin ipinle Eko todun 2015.

Bo tile je pe Olaniyan so pe looto loun jebi esun ti won fi ka noun, sugbon ki ile ejo boju aanu wo oun. Onidajo Paul so pe oun ko ni fun ni anfaani pe ki won gba beeli e titi ti ojo igbejo miran yoo fi waye.

Inu iberubojo lawon ebi Olaniyan wa bayi nitori won gbagbo pe ile ejo le so okunrin naa sewon.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI