Ipenija nla ni mo ba pade nile oko – Omo Batili Alake - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2017

Ipenija nla ni mo ba pade nile oko – Omo Batili Alake



Nidi ise orin Fuji lorileede yi, odu ni Alaaja Kuburat Oritoke to je okan lara awon ti Oloogbe Alaaja Batili Alake ko nise orin Waka ko too jade laye, sugbon latigba tobinrin naa ti gba iyanda lo ti n la kaka lati ri oluranlowo lati se awo rekoodu re akoko jade, sugbon ti ko tii ri.
 
Alaaja Oritoke
Alaaja Oritoke nigba to n ba AWIKONKO soro laipe yi nilu Abeokuta lo ti so awon ipenija ati adojuko to ba pade, eyi ti ko je ko tii se awo rekoodu jade lati odun 1984 to ti gbominira lodo oga e, Batili Alake to ko o nise naa.

O so pe awon oko toun n fe lo n se sababi ifaseyin ati ijakule toun ba pade lodo awon to ye ko ran oun lowo lati gbe orin jade, koun naa si di gbajumo laarin awon olorin Fuji, paapaa ni ti orin Waka toun yan laayo nitori pe won ko fe koun korin.

“Awon oko ti mo n fe nigba yen, opo won ni won je idena lodo awon to ye ko ran mi lowo, sugbon igba ti mo wa da duro, ti mo sunmo egbe FUMAN, ti mo n sunmo awon agbaagba bi alaga, ti won si n mu mi jade, lo ti n fi okan mi bale pe laipe, maa se rekoodu jade. Mi o tii so ireti nu wipe mi o le se rekoodu jade, niwon igba ti mi o bai ti ku, mo nigbagbo pe oluranlowo n bo.”

Omo bibi ilu Ago Iwoye yi so pe leyin toun pari iwe kefa, iyen pamari siisi ni baba oun so pe koun ma da ara oun laamu lati lo sile iwe mo nitori awon eeyan ti so pe ise orin lounmaa se toun ba dagba. “Won wa mu mi lo si odo Oloogbe Batili Alake ni Ijebu Igbo lati lo ko ise orin, ti mo si lo odun mejo nibe. Odun 1977 ni mo de odo Batili Alake, 1983 ni mo se firidoomu, ti mo gbominira.

“Mi o ko ise miran, nigba ti mo ti mo pe ise orin ni mo maa se. A maa n se odun kan lodo wa ti won n pe ni Sofari, ti a ba ti n se odun yen, emi ni mo maa n ko awon omode jo, ti a maa maa korin kaakiri aba, ti won a si maa nawo fun wa. Ibe ni won ti so fun baba mi pe ki won mu mi lo sibi ti mo tile ko ise orin nitori pe ona mi niyen, bo tile je pe mi o ni lokan tele pe ise orin ni maa se. igba ti mo ti de odo oga mi, ti mo ri bi a ti maa n lo korin kaakiri, ti a tun n se rekoodu, lo je ki okan mi la sibe pe ki n maa baa lo bee.”

Nigba to n soro nipa awon ti won jo bere orin, atawon to bere orin leyin e, o lawon tawon job ere ise orin po, “sugbon mo saaju Pasuma bere sii korin, 1984 ni mo ti n korin, o bami lenu ise orin ni. A jo maa n pade lode, to maa n ki mi daadaa. Sugbon niisin yi, ko dami mo mo nitori pe eeyan ti po fun un.” 

Bee lo so pe awon rekoodu toun ati oga oun jo ko koun too kuro lodo e le ni mewaa bo tile je pe oun ko le ranti eyi tawon jo koko se mo, nitori pe orin ti po toun naa ti ko, sugbon ti ko tii jade nitori ai ri oluranlowo to le gbe oun jade.

O wa rawo ebe sawon eeyan pe ki won siju aanu wo oun lati ma je ki talenti oun ku. O ni oun na ko duro, nitori pe awon to ye koun sunmo loun n sa gbogbo agbara oun lati rii pe oun naa se rekoodu toun jade nitori pe orin wa nile repete lati fi se rekoodu.

Bakanna lo so pe “Ko tii si olorin waka miran to si dide latigba ti Batili Alake ti ku, atipe emi ni Olorun fee lo lati gbe orin Waka dide pada, ti m ba ri eni to le ran mi lowo.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI