Osu yi ni won fee sinku Pasito Ajidara o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2017

Osu yi ni won fee sinku Pasito Ajidara o

Kii tun se iroyin tuntun mo pe agba gbajumo osere tiata nni, Oloogbe Omoba Samuel Adesina Adesanya, topo mo si Pasito Ajidara, eni to je Gomina egbe osere TAMPAN nipinle Ogun ti jade laye lojo Abameta Satide to koja lo lohun leni odun merinlelogota (64). Osibitu kan ti won poruko e ni Mercy, to wa ni Panseke Abeokuta lokunrin naa dake si, leyin bii wakati merindinlogbon ti won kede pe o nilo iranlowo owo to to milionu meedogun naira lati fi sise abe ti kidinrin re ti ko sise daadaa mo fun un.

Pasito Ajidara
Lojo Aiku Sande to tele lawon omo egbe Theatre Arts and Movie Production Association of Nigeria, TAMPAN ti seto lati yan igbimo ti yoo se kokari eto isinku oloogbe naa, eyi ti Ogbeni Bolaji Amusan, Mista Latin je alaga igbimo naa.

Gege bi Mista Latin ti so bi eto isinku naa yoo se lo fun AWIKONKO lojoru Wesde to koja yi, o ni ojo Eti Fraide ojo kerindinlogbon osu yi ni won yoo sinku Pasito Ajidara, bo tile je pe Ojoru Wesde ojo kerinlelogun lawon yoo ti bere eto isinku naa nilu Abeokuta.

Mista Latin tesiwaju, o ni ojo kokandinlogun osu yi lawon ebi Oloogbe ti koko fowo si, sugbon awon je ko ye won pe ti won ba fee kawon osere ti okunrin naa je Gomina won nigba to wa laye se ayeye alarinrin fun un gege bi eye ikeyin, ki won je kawon se nigba tawon mu naa, tawon ebi si gba si won lenu.

Nigba to n so bi eto naa yoo se lo, Ojoru Wesde ti won yoo bere ayeye ikeyin fun un lo so pe won yoo gbe loo si gbongan asa ibile, iyen Cultural Centre to wa ni Kuto niluu Abeokuta nibi ti won yoo ti te sile faraye ri, leyin naa ni won yoo gboku e loo si kootu to wa ni isabo nibi ti okunrin naa ti sise nigba to wa laye, ko to di pe won gbe loo sile fun isin aisun onigbagbo.

Lojo keji tii se Tosde ni won yoo tun se aisun onigbagbo fun un nile e, bi won ba pari e ni awon osere tiata yoo se ale awon osere fun un, eyi to seese ko waye ni Cultural Centre.

O tun so pe lojo Eti Fraide ni won yoo wa se isin ikeyin fun un nile e to wa ni Oluwo, Abiola Way, bi won ba si se pari e ni won yoo fi eeru fun eeru, eepe fun eepe, bi won si ti setan ni ayeye wejewemu yoo waye legbe ile e nibe.

Nigba to n soro nipa iku okunrin naa, Mista Latin so pe kii se pe iku okunrin naa ba awon kan lojiji nitori awon ti mo ailera e, o ti le ni odun kan abo tawon ti mo, gbogbo igba to ni okunrin naa fi saisan, se lo ni o so pe agbara oun ko fee ka itoju naa mo.

O ni o so pe owo kan wa to fee gba lowo ijoba gege bi owo ifeyinti iyen lo ni lokan pe toun ba gba, oun yoo fi toju ara e, se gbogbo nnkan to ba fee se, nitori o ni o je eda kan ti kii fee fi tie ni awon eeyan lara.

O ni o se ni laaanu pe ko rowo naa gba lowo ijoba titi ti olojo fi de. O ni nigba to fee yiwo ni iyawo e so pe kawon se ikede lori ero ayelujara fun iranlowo, tawon si tipase e rowo die.

Bo tile je pe titi di asiko ti a n ko iroyin yi jo ni iyawo oloogbe naa, iyen Arabinrin Atinuke soro, sugbon awon omo e, Arabinrin Ogunsina Adedayo Adeshina ati Adesanya Adedamilare Oluwaseyi ba wa soro pe ibanuje niku Baba awon si n je fawon nitori pea won ko le gbagbe bawon se jo maa n se tawon ba wa ninu ile atawon eko to ko won ko too ku lawon ko le gbagbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI