Ki lo wa laarin Olori ati Arewa? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 29, 2017

Ki lo wa laarin Olori ati Arewa?

Ibeere tawon eeyan n beere ni pe ki lo wa laarin awon gbajumo sorosoro to je omo egbe FIBAN mejeeji nni, Queen Toyin Adeniji, Olori ati Muibat Oseni, iyen Arewa.

Arewa ati Olori
Bo tile je pe ko seni to le so pato nnkan to wa laarin awon mejeeji sugbon nkan to je ki won maa beere ibeere naa ni bo se je pe ibi ti won ba ti ri Olori naa ni won ti maa ri Arewa.

Yato si wipe awon mejeeji je sorosoro lobinrin, won ni nnkan min in tun pa won po to yato si ise redio, ohun lo se je pe lojo ti Arewa se ojoobi e laipe yi, Olori lo n se kukukeke, to n gbawaju gbeyin bi eni pe won je omo iya.

Bi e ba si ti ri obinrin meji ti won jo n se wole wode ni gbogbo igba, o ni lati je pe oro asiri kan wa laarin won ni, atipe gbeborun lo maa n saba wa ninu oro awon obinrin, ti won ko si fe ki enikeni mo idi abajo to wa laarin won, nitori pe bi e ba bi awon mejeeji pe ki lo n sele, ko si nkankan ni won maa so.

Fun eni to ba ri awon mejeeji ti e wo aworan won yi, bo ya e le ba wa beere pe ki lo wa laarin won ti ajosepo won fid an monran to bee.

Ko kuku seni ti AWIKONKO ko le gbe oro e jade sita. Sugbon sa o, adura AWIKONKO nipe gbogbo eni to ba fee da aarin awon mejeeji ru ni Oba oke maa da ona e ru. Iko kii ko omo ejo lese, gbogbo ibi ti e ba n gba ni Adedaa yoo maa tele yin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI