Nitori FUNAAB; Alake rawo ebe sijoba apapo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 29, 2017

Nitori FUNAAB; Alake rawo ebe sijoba apapo

Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo, Okukenu kerin ti rawo ebe sijoba apapo lori oro ileeko fasiti ise ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta nitori eka ikekoo kan to n ri si kiko nipa isakoso, iyen College of Management Sciences, COLMAS ti won fagile laipe yi.
 
Alake tile Egba
Ojo ketalelogun osu yi ni Aare Baroyin ile Egba, Olootu Layi Labode ti gbowo Oba Alake rawo ebe ninu leta alabala marun to fi ranse si Aare orileede yi, Ogagun Muhammadu Buhari; igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo; Aare ile igbomi asofin agba, Dokita Bukola Saraki; Onarebu Dogara; Senato Lanre Tejuoso; Senato Buruji Kashamu; Senato Gbolahan Dada; Onarebu Segun Williams; Onarebu Mukaila Kazeem ati Ojogbon Abubakar Raheed to je akowe igbimo to n ri si oro ile eko fasiti lorileede, eyi ti eda e te AWIKONKO lowo.

Bi e o ba gbagbe, laipe yi Minisita foro eko lorileede yi ti pase pe ki awon fasiti to doju ko ila eko kan tesiwaju ninu ilana eko ti won yan laayo, ki won yo awon ilana eko ti won ko mo won mo sugbon ti won n sise lori e kuro. Eyi tab a opo awon fasiti, Poli atawon ile eko giga miran lorileede yi, to si fee fa owo aago won seyin.

Nibe ni Alake ti so pe ki ijoba apapo boju aanu wo fasiti FUNAAB atawon akekoo to ti wa lenu eko naa ko too gbe ase naa jade, nitori pe ko sibi ti won fee lo, atipe saa awon akekoo kan ti fee pari, to si je pe se lawon akekoo kan sese wole, ko too dipe won gbe ase naa jade.

O so pe opo awon eleto eko, obi, alagbato, osise, akekoo atawon toro naa kan nipinle Ogun ati agbegbe e lo ti fehonu han, ti won si ti wa n ba oun lati wa nnkan se soro naa, eyi to si se oun laanu wipe oro naa n fe abojuto daadaa, atipe ki won yi ase naa pada.

Alake ran ijoba orileede Naijiria leti pe osu kesan odun 2011 ni Fasiti FUNAAB da eka ikekoo COLMAS sile latari ase ijoba to koja lo, iyen ijoba Dokita Ebele Jonathan to pase pe ki awon fasiti ma se koju mo eka ikekoo kan soso, ki won yabara, ki won si fi awon eto eko miran si ilana eko ti won n ko nitori ki ise le rorun fawon ile eko giga to ku.

O ni bi won ba so pe ki fasiti FUNAAB dawo eka ikekoo naa duro, a je pe won ko fe kawon akekoo je anfaani imo igbalode nipa isakoso (Management Sciences) bii isiro (Accounting), ile ifowopamo ati isiro owo (Banking and Finance), eto sile (Business Administration) ati eko bi a se n da ise sile (Enterpreneurial). O ni opo awon akekoo to le ni egberun mewa lo saba maa n gba foomu si awon eka ikekoo yi lodoodun tawon si ma n gba to eedegbeta ninu won gege bi ajo JAMBU se maa n fun won.

Alake tesiwaju pe eka ikekoo yi ti won da sile ni Abeokuta, Makurdi ati Umudike ti mu ki eto oro aje orileede yi lo soke paapaa lawon ilu to faaye ile gba won lalejo. Tawon ti ko rowo mu lo senu si ti n fun awon alaini lounje.

Gege bi AWIKONKO se gbo, akekoo to to egberun kan ni won ti keko gboye laarin odun mefa ti won da eka ikekoo naa siile. Bee lo si je pe opo awon eeyan nipinle Ogun lo je pe owo to n wole fun won ko to n kan, eyi ti ko si ni fun won lanfaani lati mu awon omo won lo sile eko giga towo won lo soke gegere.

Alake ni oro naa n fe agbeyewo ni kankan nitori pe awon igbese to tun le fa oro aje orileede yi lo seyin ni Minisita foro eko lorileede yi gunle, ki won si tete wa atunse si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI