Mi o muti yo o, iwa rere leso eniyan – Omodo-Agba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Mi o muti yo o, iwa rere leso eniyan – Omodo-Agba

Omodo Agba
Agba ogbontairigi sorosoro nni nipinle Ogun, Alaaji Moruph Adegboye, tawon eeyan mo si Omodo-Agba ti so pe kii se pe oun muti yo lojo ti Oloye Adeifa Sogbeinde sayeye odun ifa olodoodun to maa n se, eyi to waye logbon ojo osu to koja nilu Abeokuta.
 
Omodo Agba soro yi lakoko to n ba AWIKONKO soro lojo aje Monde to lo lohun ni ogba olopaa to wa ni Eleweran Abeokuta lakoko tawon olopaa n foju awon odaran han fawon oniroyin.

O so pe gbogbo igba ti inu oun ba n dun loun maa n se bebe fawon eeyan paapaa awon to sunmo oun lakoko ti won ko ba lero. O ni wipe oun ko maa n na owo loju agbo ti a so yen, kii se ooto nitori pe oun ko le se koun ma na owo.

Bakanna lo so siwaju pe iwa rere leso omo eniyan laye, nitori e lo se je pe o dara ki eeyan maa se daadaa ni gbogbo igba, atipe ojo iwaju lo ye ki eda maa ro laye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI