Mi o ba ti fise orin Fuji sile tipetipe – Uncle Spaghetti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 15, 2017

Mi o ba ti fise orin Fuji sile tipetipe – Uncle Spaghetti

Ilumooka olorin Fuji nni to filu Ekoo sebugbe, Adeboye Ajani topo mo si Uncle Spaghetti ti so pe oun ki ba ti fise naa sile tipetipe latari awon isoro ati ijakule to n ba pade lenu ise naa nigba to bere, ko too di pe o jade sita gbangba faraye.

Uncle Spaghetti
Alaaji Abass Akande Obesere, iyen Omorapala lo foun ni oruko inagije Uncle Spaghetti toun je leyin tawon pade ni oteeli kan to ti loo sere ni Isolo, Eko lodun 2010.

O soro yi lose to koja nibi eto ibura tegbe awon onifuji ipinle se nigba to n bakoroyin wa soro lori irinajo e sidi ise orin atawon ipenija to ti koju nidi ise naa lati odun 2000 to so pe oun ti bere sii korin Fuji bo tile je pe o so pe oun ko ni oga nidi ise orin, sugbon oun ni eni toun n wo gege bi awokose nigba toun bere, eni naa lo pe ni Alaaji Raimi Ajao Tope Nautical.

Uncle Spaghetti tesiwaju pe okan lara awon ololufe Obesere lo je kawon pade lodun naa lohun, igba yen lo ti gbo orin lenu oun, to si so pe a dun mo oun ninu to ba le fi Uncle sinu Spaghetti toun je, nitori pe Spaghetti Fuji lasan loun n je nigba naa. O so pe eyin toun gba oruko naa loun se awo rekoodu eleekeji toun pe ni Unbelievable jade lodun 2012 nitori pe odun 2010 loun ti koko se rekoodu akoko jade toun pe ni Promise.

Nigba to n soro lori iriri ati ipenija to ti koju lenu ise naa, o so pe ibaju nla lo maa n je foun toun ba n ranti awon ijakule to ti ba pade lenu ise, nitori to so pe aimoye igba lawon alaanu oun ti ja oun kule, to si je pe ojo to ba ye ki won mu ileri ti won ti se foun se, ni won maa so pe ko sona nibe mo, eyi to maa n ba oun ninu je pupo, ti ise naa si fee su oun, bo tile je pe oun a tun yii ro.

Bee lo so pe laifu akoko toun pe ni Better Life lo gbe oun jade faraye, tawon eeyan si bere sii pokiki oun nigba na ni Agege. Gbogbo to n gbo orin na ni won ro pe Tope Nautical lo n korin nitori pe oun loun wo gege bi awokose nigba toun bere.

Uncle Spaghetti ni aimoye ere ofe loun ti se, tawon onilu si ti tuto soun loju. “Igba mi in wa tawon omo onile ti so pe a o gbodo sere ti a ba de aba won. Mi o le ka iye igba ti mo ti jiya lode ere. Olorun lo ko mi yo ninu ijamba moto ti mo ba pade leemeji otooto lojo kan soso lona Mowe ati Kobape nitori pe se ni moto wa dori kodo tan patapata.”

O ti e so pe won ti fi Eko ha noun ri nitori pe ko pe toun de ilu Eko ni won yo foonu lapo oun nibi oku iya Alaaji Saheed Osupa. O ni ki irawo oun baa le tete tan loun fi kuro nilu Abeokuta, toun si ko gbogbo eru oun lo silu Eko.

Bakanna lo so pe ajosepo to dan moran lo si wa laarin oun ati Omo Rapala, Saheed Osupa, Alabi Pasuma, Atawewe, Malaika, Remi Aluko atawon agba olorin Fuji to ku nitori pe oun mu won gege bi baba ati asaaju oun nidi ise orin tawon jo n ko.

O lo akoko naa lati kilo fawon omo onifuji ti won n gbojusoke wo awon asaaju pe ki won lo jokoo je, nitori awon to baa n bu asaaju won kii pe, atipe ijiya wa fun riu awon eeyan, yala eni to wa ninu egbe ni tabi awon ti ko se egbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI