Mi o ni soro lori isinku Moji Olaiya – Bisi Omologbalogba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 20, 2017

Mi o ni soro lori isinku Moji Olaiya – Bisi Omologbalogba

Bee ni Ijoba ipinle Ekiti tun ti dide iranlowo

Bisi Omologbalogba
Bo tile je pe ijoba ipinle Ekiti labe Gomina Ayodele Fayose, Osokomole-1 ti so pe oun yoo sagbateru gbogbo eto to ba ye lati gbe oku Oloogbe Moji Olaiya pada wa sile lati ilu Canada to ku si latari bi omo e, Adun se ko jale pe won ko gbodo sin iya oun leyin oun, a fi koun foju ri.

Ko je tuntun pe eni to sunmo gbajumo Oloogbe Moji Olaiya ju ninu awon osere tiata ni Bisi Ibidapo-Obe topo mo si Bisi Omologbalogba nitori pe ore kori-kosun ni won je, to si je ko si nnkan tawon mejeeji ko mo nipa ara awon, paapaa nipa oro idile won.

Bi e ba so pe tegbon taburo ni won, e o paro, bi e ba si so pe ore timotimo ni won, e o jayo pa nitori pe ibi ti e ba ti ri Moji Olaiya naa le ti maa ri Bisi Omologbalogba bo tile je pe won kii se eje kanna an.

Nigba ti won woo pe tani won tun le pe lati beere oro lowo e lori bi isinku Oloogbe naa yoo se ri, latari wahala to tidi e yo nipa ibi ti won fe sin in si, ohun to so nipe oun ko loro lati so nipa.

Bisi Omologbalogba so pe ki won ma yo oun lenu, ki won ma beere iku to pa ore oun lowo oun, ki won si fi oun sile na nitori pe ara oun ko tii bale, oun ko tii mo ibi toun ti fee bere, atipe ta loun yoo tun foro lo.

O so pe ironu iku enikeji oun lo si wa lara oun atipe eni to ba fee mo nipa isinku Moji Olaiya, ko maa bo mi Magodo lati wa foju ri nnkan to n lo.

Yomi Fash Lanso
Nigba toun naa n soro nipa bi isnku Moji Olaiya yoo se lo, Yomi Fash-lanso to farahan ninu fiimu akoko ti Moji Olaiya yoo ti kopa, iyen Owo Ale so pe enikan soso lo si lodi si wipe ki won sin Moji silu Canada ni omo e Adun to je akeko ile eko Backcock ni Remo. O loun nikan lo si le so idi e to fi so pe dandan ni ki won gbe iya oun pada wa si Naijiria.

Yomi so pe bi eeyan ba maa gbe oku wa lati Canada, o kere tan, egberun metadinlogun dola ($17,000) lo maa na won, atipe o wa ku sawon ebi naa lowo lori igbese ti won ba fee gbe.

Nigba to n soro lori aheso wipe oro naa lowo aye ninu nipa bawon osere tiata se n fo sanle ku lasiko yi, Yomi so pe oun ko nigbagbo ninu wipe ise aye ni, nitori pe onikaluku lo ti ni akosile igba to maa ku.

O ni opo eeyan lo n ku lojumo, sugbon tawon to loruko lawujo ba ku, orisirisi oro lo maa maa jade sita. O ni ki won gbenu kuro lori wipe ise aye ni, nitori pe awaya malo kan ko si.

Sugbon ni bayii, AWIKONKO gbo pe oko ti Moji bimo osu meji yi fun, eni to filu Abuja sebugbe ti wa nilu Eko lati Ojobo Tosde toro naa ti sele, tiroyin si ti kan kaakiri agbaye, bo tile je pe oun naa gba pe ki won sin iyawo oun si Canada nitori aisi owo lati fi gbe e wale ko too dipe ijoba ipinle Ekiti dide fun iranlowo.

Aago merin irole ojo Eti Fraide to koja yi lo ye ki won sin Moji silu Canada pelu gbogbo eto ti won ti se nibe ni ilana Musulumi, sugbon ti won da won lowo ko pe ko jo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI