Nibi ayeye Wolimo ijo Salamu-Llahi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Nibi ayeye Wolimo ijo Salamu-Llahi

Gege bi asa ati ilana ti awon elesin alaafia nni, iyen Islam se laa kale pe dandan ki awon ti won ba lo sile keu lati lo ko eko nipa bi a ti n keu, ka kurani ati bi a ti n fa aaya se Wolimo, eyi ti yoo je ki gbogbo aye mo pe looto ni won la ile keu koja.

Awon meteeta
Lojo Aiku Sande to lo lohun ni Imaamu Muhaleem Iskeel Olakewu labe ijo Salamu-Llahi Centre for Islamic Culture to fikale silu Abeokuta se Wolimo fawon meta to kun oju osuwon lati gba iyanda.

Awon meta naa ni Obadara Fathia, Odedina Muh Faruuq ati Obadara Ibrahim. Lojo naa ni won tun lo anfaani naa lati fi se ikowojo fun ijo ti won n ko lowo.

Okan lara obi awon omo to se Wolimo naa, Ogbeni Akeem Obadara nigba to n bakoroyin wa soro so pe idunnu ati oriire nla lo je foun wipe meji ninu awon omo oun se aseyori ninu eko ti won lo ko naa.

Arabinrin Obadara nigba toun naa n soro so pe odun to koja lo ye kawon omo naa ti se wolimo yi sugbon oun gbogbo lo ye Olorun to fi je pe odun yi ni won se, nitori pe won ti dangajia ninu kika kurani.

Imaamu Olakewu wa lo akoko naa lati fi dupe lowo Olohun fun anfaani ati ona ti ayeye naa gba waye atawon agbaagba ninu esin naa to wa sibe lati ilu Ibadan.

Bakanna lo wa gbawon Musulumi lamoran lati maa ran awon omo won lo sile keu ki won si tun rii daju pe won n se Wolimo fun won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI