Kayefi loro ara to san pa Fausat lori beedi si n je fawon araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Kayefi loro ara to san pa Fausat lori beedi si n je fawon araalu

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo lawon araalu Gbayunre nijoba ibile Ado-Ota, ipinle Ogun si fi wa ninu iporuru okan lori ara kan to san, to si seku pa arabinrin kan ti won poruko e ni Fausat, iyen iya Ayuba, eni ti won so pe ojo ori e ko tii ju aadota odun lo.

Aala awon onisango
Gege bi AWIKONKO se gbo, lojo kerin osu yi ni nnkan bi aago mokanla asale ni won so pe ojo kan ro, to si san ara, ara yi ni won lo o wole to Fausat atoko e, tawon eeyan mo si Oluso lori beedi ti won jo sun si,  to si seku pa a.

Bo tile je pe se ni won so pe aditu loro ara naa je fawon bo se je pe eemeeta otooto ni won ni ara naa san wonu ile naa, to si ba nnkan je, yato si wipe o seku pa Fausat.

Bawon kan se n so pe oro naa lowo ninu nitori pe ara kii deede san paayan, bee lawon kan n ni ise buruku to wa lowo oko arabinrin naa, iyen Ogbeni Olorunwa ti won ni Oluso ni lo dahun lori iyawo e, to si so awon ebi e sinu ekun ati laala ti won n ba kiri lowo bayii.

AWIKONKO gbo pe ko tii ju odun marun ti obinrin naa ko de odo okunrin naa ni isele buruku yi waye. Bakanna la tun gbo pe okunrin naa kii baayan se ladugbo, paapaa nilu Gbayunre lati nnkan bi odun marundinlogoji ti won lo o ti wa pelu won.

Ogbeni Oatinwo, Alaga CDA
Alaga idagbasoke agbegbe Irewolede toro naa ti sele, Ogbeni Olatinwo Saka Adesina, nigba to n IROYIN OWURO soro lojobo Tosde ose to koja lori isele naa so pe aditu loro ara naa si n je fawon nitori pe awon ko tii ni ifokanbale lori e latigba toro naa ti sele.

Okunrin naa so pe inu isooru ni soosi loun wa lale ojo naa, nigba tawon gbo bi ara naa se san, ohun ti ara naa gbe yato sawon ara to maa n san nigba tojo baa n ro, maiki gan an jabo lowo oga akorin, koda, awon eeyan inu soosi gan fee takiti lojo naa.

O ni ko tii ju bi ogun iseju lo toun ti ri awon agbaagba ladugbo ti won wa ba oun pe ara to san naa ti pa iyawo Oluso, sugbon awon ko tii le wole ayafi ti ile ba tubo mo si.

O tesiwaju pe laaro kutu ojo keji, iyen ojo Wesde lawon ri awon kan ti won wa so pe eran awon sonu, ohun lawon n wa. O ni oro naa ko tete ye awon iru eran ti won n so, sugbon nigba to ya, won je ko ye wa pe ara to san naa ti paayan.

Ogbeni Olatinwo so pe lojobo Tosde lawon bere igbese ni pereu nigba tawon rii pe kii se kekere loro naa nitori oju tawon fi wo. O ni esekese lawon ti bere igbese lati setutu lori ki isele naa ma baa tan kaakiri ilu.

Olori Ebi
Ninu oro ti olori ebi ilu Gbayunre, iyen Oloye Dada, o so pe bo tile je ara kii deede san paayan laini idi kan ni pato sugbon oju Olorun lo to gbogbo e, o ni ohun ogbologbo iwa buruku lo wa lowo Oluso naa nitori pe iran kefa loun je leyin ti won ti da ilu Gbayunre sile.

O ni iru nnkan bayii ko sele ri latigba ti ilu naa ti wa, iyalenu loro naa si n je fawon, nitori pe sadede lawon gbo pe sango mu enikan ni soosi Oluso, nibe ni aya oun ti ja pe afigba ti okunrin yi ko wahala wo inu ilu wa ba awon.

O tesiwaju pe o ti le ni ogbon odun tawon ti jo n gbe ilu ti ko sib a enikeni se papo. O ni awon ti gbe igbese lati fejo e sun awon olopaa paapaa ijoba ipinle Ogun lati wa wa nnkan se si oro e.

Suraju to je okan lara awon omo oloogbe naa nigba to n soro pelu omije loju so pe ni nnkan bi aago kan oru ni won pe awon pe ara san pa iya awon lori beedi, sugbon ibi tawon wa ko le je kawon foru rin, sugbon nigba tawon de laaro ojo keji tawon de ile naa, lawon sese ri nnkan to sele.

O ni bawon se wole tawon ri iya awon nibi to sun si lawon eeyan ti n pariwo pe kawon ma fowo kan nitori pe se ni ara naa gbo jalajala to si je ori e nikan lawon fi daa mo pe iya awon ni.

Suraju so pe oun ko le so pe nnkan bayii pato lo gbe iya awon de odo Oluso naa nitori pe o ti le ni odun meje ti iya awon ti kuro lodo baba awon ni Idiroko, ti ko si si omo Kankan lodo won lasiko naa.

O ni ko tii ju bi odun marun lo tawon gbo pe odo Oluso naa ni iya awon wa bayii, tawon si wa sibe lati mo ibi ti iya awon n gbe. o ni ohun tohun yoo tun gbo nipe ara san pa iya awon.

Ohun ti AWIKONKO tun ri gbo nipe opo igba ni won ti mu Oluso yi lo si tesan olopaa lori pe o ji eran, adie, isu, bulooku gbe, eyi ti won lo fi n ko soosi e naa. Bee la tun gbo pe okunrin naa kii ba eeyan se ladugbo.

Sugbon fun bii wakati mefa ti asojukoroyin AWIKONKO fi wa nilu Gbayunre lati ri okunrin ti isele naa sele nile e ni a ko fi ri, oun ti a gbo nipe lesekese ti okunrin naa gbo pe oniroyin ti wa nitosi lo tin a papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI