Ojo wo ni Emir fee jawo ninu oti amupara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 26, 2017

Ojo wo ni Emir fee jawo ninu oti amupara

Oro naa ti n koja oju tawon eeyan fi n wo bayii, o si ye kawon omo egbere tiata, paapaa awon TAMPAN tete wa nkan se si bi won ko ba tun fe maa nawo lori aisan omo egbe won mo.

Nibi ayeye ale ojo awon osere, Artiste Night tegbe osere TAMPAN lorileede yi se fun Gomina won to doloogbe laipe, iyen Pasito Ajidara loro kan tun ti yoju, eyi to si soju AWIKONKO.

Okunrin kan ni o, to je okan lara awon agba irawo osere tiata nipinle Ogun, Ogbeni Kayode Akindina tawon eeyan mo si Govna ati Emir, paapaa awon kan a tun maa pe e ni Sa-K (Sirkay). Bo tile je pe won ti n reti lati aaro pe ko de si gbagede Asa ti ayeye naa ti waye lojobo Tosde to koja yi.

Sugbon bi okunrin ti won n pe ni Emir se sokale ninu moto e pelu bobo kan boya maanu de ni ka pe ni, iyen Olu Olowogemo topo mo si Harijan, ibeere akoko ti Emir maa koko beere lowo eni to lo pade e ni pe “se o gbe ororo wa sa, moto e da, nibo lo paaki si?

E gbo, ki lo n je ororo? Bawo leeyan yoo se maa wa ororo kiri, lai kii se pe o fe din eran tabi eja, sugbon awon kan to ja si lo so fun AWIKONKO pe kii se ororo lasan lo n beere fun, won ni Oti Akohoolu lo n je be.

Lara awon ti won jo duro lo so pe “haha daadi, ororo ke, nibi isinku Gomina yin”, idahun to fi nipe gbenu e sohun, kilomode e mo.

Se ni AWIKONKO la enu sile, ti ito fe maa jabo, kawon eeyan to so pe e panu de. Se ni Emir n se bi eni pe ororo yi ni eje to n gbe e rin, abi ka so pe ororo yi ni epo to n gbe e sise.

Bee, o le dabi ere tabi awada, sugbon ooto oro ko le ni ka ma so ohun sita, e kilo fun Buoda Emir, iyen SirKay wipe oro ti won n mu ti n poju, diedie ni ki won maa se e, ko da fun aago ara, paapaa agbalagba bii ti won.
Boya won si ro pe omo kekere si lawon ni, ko ye mi rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI