Opo awon pasito lo si n wo akosejaye omo won – Oloye Adeifa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Opo awon pasito lo si n wo akosejaye omo won – Oloye Adeifa

Ti a ba n so nipa Babalawo to ko ise ifa, to si n se aseyori lowolowo bayii nilu Abeokuta tii se olu-ilu ipinle Ogun, odu ni Oloye Adeifa Shogbeinde,  kii se aimo foloko. Sugbon bi e ba pade e nita, e o le mo pe ise Babalawo ni o n se. Oloye shogbeinde ba AWIKONKO soro nipa igbesi aye nidi ise Babalawo to yan laayo. Eyi lawon oro to so kale.


AWIKONKO: E ku deede asiko yi, e je ka mo yin ati bi e se je
Oloye Adeifa
ADEIFA: Oruko temi ni Oloye Dokita Adeifa Shogbeinde. Emi ni Asiwaju Onifa ti Adigbe. Mo je Balogun Egbe Ifadola tile Egba. Emi naa tun ni Olori Egbe Ifa Modupe tile Adigbe.Emi ni Olugbani nimoran egbe Alaragbo Isese ti Ikereku nile Egba. Emi ni Akinrogun Egbe Ifa Lolaye tilu Gbagura. Emi ni Babalaje Irawolagba Social Club to wa ni Adigbe. Bakannaa ni mo tun je Baba Egbe Unbeatable Sister Club to wa ni Ijeja Abeokuta.

AWIKONKO: Babalawo to mo ifa dujuduju ni yin, bawo ni irin ajo yin sidi ise ifa?
ADEIFA: Ese gan. Mi o tii ju omodun meedogun lo nigba ti mo bere sii ko ise ifa yii. Nigba ti baba mi ku ni odun 1991, mo ni lati lo si odo oga mi, iyen akobi baba mi lati lo tesiwaju ko too di pe mo gba iyanda, temi naa si da duro laaye ara mi.

AWIKONKO: Bawo ni iwa awon babalawo se ri lode oni?
ADEIFA: Ibi owo la ti n ba babalawo, e o le ri babalawo nibi ti won ti n se isekuse tabi muti, se iranu tabi se orisirisi iwa ti ko ye omoluabi. Ibi owo ni a ti n ba won.

AWIKONKO: Opo eeyan lo je won n sa fun isese nitori pe won gbagbo pe ise ibi ni won fi n se, ki le le so sii?
ADEIFA: Tipetipe lawon eeyan ko fee sunmo isese, sugbon nnkan ti yato bayii nitori pe oju ti la, nitori pe awon ti won o sunmo isese tele ni boya ti isese ti wa ni iran won ri ni won ti n pada wa sinu e bayii. Awon ise kan wa lowo mi bayii to je pe awon yen ko si isese ni iran won, to je pe idile alaafa ni won ti wa, sugbon nigba ti won rii bi isese se n lo, won ni lati sunmo on, mo si so pe ki won lo te ifa, ti won si gba lati se. Aye atijo lawon eeyan ti n sa fun, kii se laye ode oni. Ko si n kan tawon alakowe n se lasiko yi tawon babalawo tabi awon onisese kii se. Babalawo ti n gun moto to dun n wo loju, koda, ile to ju tawon pasito atawon alaafa lawon babalawo n ko bayii.

AWIKONKO: Ki ni e le so nipa iyato to wa laarin ori bibo ati ifa tite, atipe ki ni anfaani to wa ninu mejeeji?
ADEIFA: Ibeere gidi le beere yi. Anfaani to po lo wa ninu e. Nigba ti alaye ti da aye ni won ti n bo ori, ninu odu ifa kan ni Ajala ti pe Afuape leyin to bo ori e pe ibi to la  ninu ori to la mole yen ni won a maa pe ni awuje omo, ti o ba de ile aye, o ni ojo ti ori e ba ti gba eku, ki o fun, ojo to ba gba eye, ko fun, o ni bo ba je eja tabi eran lo gba ko fun, oka yen maa maa di diedie. Oni ojo ti won ba ti n se adura fun, ibe ni adura yoo maa gba wole. Eni to ba bo ori e, ki nkan e le da ni. Ti ko ba si nkan yi ti Ajala se nigba naa lohun, eeyan ko le se adura ko gba. ti won ba n bo ori, nkan ti won ba fi bo ori yen, eni ti won bo ori fun gbodo je ninu e. Ori yato si ifa nitori pe ori kii se isese. Ayanmo ti Olodumare da mo wa ni ori. Ni ti ifa tite, kii se gbogbo eeyan lo n te ifa, nitori pe a maa n ri omo babalawo miran to maa so pe oun ko te ifa, ti ko si nii te. Awon ti Olodumare ko ifa mo lo n te ifa. Aimoye omo babalawo lo wa to je pe pasito ni, to si ti di olokiki. Sugbon elomiran wa to je pe ti ko ba I tii te ifa, ko le se aseyori. Won le ti waasu fun elomiran, sugbon ti ko ba te ifa, ona e ko le la. Kii se pe tori pe babalawo fee gba owo lo se maa so pe ki eeyan lo te ifa, sugbon won ti rii pe ki aye e le da, o gbodo te ifa. Sugbon ki eeyan to te ifa, won a koko bo ori e fun.

AWIKONKO: Nipa akosejaye, nje awon eeyan si nigbagbo ninu e lasiko yii?
ADEIFA: Beeni, awon kan si nigbagbo ninu e gidigidi, bo tile je pe awon kan so pe awon ko le se e, paapaa awon onigbagbo atawon elesin musulumi, sugbon mo fee so fun un yin pe awon pasito ijo kookan si n wo akosejaye awon omo won. Mo si sekan laipe yi to je pe pasito naa ti da soosi sile. Ifa lo si maa n so omo loruko. Emi bi apeere, ifa lo so gbogbo omo mi loruko. Pasito min in le woo pe oun ko le gbe omo oun lo sile babalawo kawon omo ijo oun wa ri oun nibe, sugbon won a ranse pe babalawo naa lati wa bawon wo akosejaye omo won. Ki aago marun too lu ni babalawo ti maa ji debe lati se nkan to fee se, ti ko si seni to maa mo si yato si iyawo e. bee naa lawon Aafa miran si n se e pelu, won o kan le so o sita ni. Akosejaye yi lawon baba wa ma n lo lati fi mo bi irinajo eda se maa ri.

AWIKONKO: Nje e o ro pe bawon oyinbo se n wa lati ko isese ile wa ko le se akoba ojo iwaju fun wa?
ADEIFA: Ko le ri be. Lowolowo bayii, oyinbo alawo funfun kan lati orileede Germany wa lodo ore mi kan to je pe ise babalawo lo wa ko, o si ti fee lo to ose meji bayii. Awa ti a ni isese yi lowo ni a o mo iyi ati pataki e, to je kawon oyiinbo fi wa maa ko lowo wa, ti won si n gbe e laruge ju wa lo. Awon oyinbo si ti n je ki a maa mo pataki e bayii. Sugbon bi mo se n baa yin soro yi, a ti n mo iyi e, nitori pe oju wa ti la. Awon kan ti n ge ika je nitori pe awon ko se isese lasiko to ye ki won se e. Opo awon pasito lo je pe won ti n se isese gidigidi. Won le ma maa se losan, sugbon loru, won n se gan an. Mo ni won lowo repete, sugbon a fi ka foruko bo won lasiri. Nitori won mo pataki e ni won se n se, ti won si n fi soosi ati oruko Jesu boju lati fi tu awon eeyan won je. Bi e ba dele babalawo, e o le ba ifa omo babalawo nibe, ifa awon aafa ati pasito ni e maa ba. Esin ni won fi n boju, ti won si n yo wa lati se isese. Ko si n kan to buru ninu ka se isese sugbon oju tawon eeyan fi n wo o ni pe boya won n paayan, eyi ti ko ri bee. Isese ni won koko n se ko too dipe awon elesin igbagbo ati musulumi de.

Oloye Sogbeinde
AWIKONKO: Gege bi asiwaju onifa ni Adigbe pelu ojo ori yin yi, ki ni awon adojuko ti e le so pe e ba pade ki e too gba ipo asiwaju yi?
ADEIFA: Awon baba wa ni won fi mi je Asiwaju yi, bo tile je pe a ni Olori onifa gbogbo Adigbe, awon ni a n pe ni Ifamodupe. Ki won to fi eeyan joye, won a koko wo eko to ko, ibi to mo ifa de ati iwa e. bakanna ni won a wo igba to bere ise ifa. Won o kii fi agba to oye nidi ise ifa. Omode bi miran wa to je pe o maa je oga le egbe baba e lori, nitori pe elomiran le tip e omo ogoji odun ko too di pe o bere ise ifa, to si je pe kekere ni elomiran ti bere. Nigba ti omodun mejo ba maa fi pari ifa, agbalagba miran le mai ti bere, oye to si maa je maa ju ti agbalagba yen lo. Won o ni woo pe tori agbalagba ni.

AWIKONKO: Kini e lo so nipa awon adojuko tabi isoro ti e ti ba pade lenu ise yii, atipe nje e ti e roo ri pe ise babalawo le fee see ti e ba dagba bo tile je pe akosejaye yin ti so o?
ADEIFA: Mi o figba kan roo ri pe ise naa ni maa fi jeun ti m ba dagba nitori pe nigba tawon baba wa n se nigba naa lohun, ise yi ko wu wa lati se nitori bi won se n se e nigba naa. Bi won ba fee jade, keke ni won maa n gbe kaakiri lati abule kan si omiran, ti won ba maa pada de sile, aso won a ti doti, nitori naa ni ko se je ki ise naa wumi lati se, nitori pe awon obinrin gan kii fe sunmo iru won lati fe. Sugbon baba mi lo so fun mi pe ise naa ni mo maa se, ti mi o si le ko oro sii lenu. Opolopo adojuko ati iriri ni mo ti ba pade lenu ise yii nitori pe nigba kan ri, mo ti gba eeyan sile ninu isoro to je pe omi fee teyin wogbin lenu, Olorun lo yo mi nitori pe mo saisan doju iku, Olorun lo ko mi yo.

AWIKONKO: Nje ko si ifigagbaga laarin awon babalawo bo ti wa nibo miran, atipe ki ni ajosepo to wa laarin eyin babalawo kaakiri?
ADEIFA: Oro yin ye mi. akuko gagara ko fe ki kekere ga wa, ko tun si ninu ise babalawo. Igba kan lo wa, sugbon ko siru e mo bayii. Ti a ba ti lo si Oke-Abola yen nigba odun ifa, gbogbo babalawo patapata lo maa wa nibe lati bura pe oun ko nii pe ori babalawo egbe lai da. Won maa ko olugbohun ati afose sile pe ki won maa fi bura, tawon toku a si maa se ase. Eyi ni ko ni fun babalawo to ba fee se omolakeji e nibi laaye lati se e.o sit un je ki irepo wa laarin wa.

AWIKONKO: Kini e le so nipa ogunjo osu kejo odoodun ti egbe awon babalawo so pe ki ijoba apapo ya sile fawon?
ADEIFA: Ese. Awon onigbagbo to ba di asiko kan, won a so pe awon n se odun Easter tabi Keresi, bakanna ni awon musulumi naa maa n se odun Ileya ati Itunu Awe. Eyi lo fa ti awa naa fi woo pe ki a ya ojo kan soto lati fi dupe ohungbogbo ti a ti ri gba lowo Orunmila, ni won fi fenu ko si ogunjo osu kejo, iyen August 20. Iyekiye ti onikaluku ba ni ni o maa fi si oju isese ti a maa n lo yen lati fi dupe oore. Se e mo pe awon oni soosi ati oni mosalasi maa n fi owo ore tabi owo ope sile, bee naa lawa naa n se. O je ojo ti a n dupe lowo gbogbo irunmale ati isese patapata. Nitori e la se wo o pe ki ijoba apapo fun wa ni olude nitori awon elesin toku naa n gba olude bi won ba n se odun tiwon. Sugbon nnkan ti ijoba so nipe bi a ba fee gba olude, ki gbogbo awa onisese patapata, iyen awon onisango, oloya, eleegun, olorisa ati beebeelo lo parapo, ki won so lu lati fenuko si ojo kan soso. Tele lo je pe ogunjo yen, awa babalawo nikan ni a maa n se, sugbon ni bayii a ti lo o pe awon onisese toku lati parapo maa lo anfaani ojo naa. Ojo ketadinlogun lati maa n bere ki a to lo si Oke-Abola logunjo yen lati fi se asekagba e.

AWIKONKO: Ayeye ifa Alaragbo ti e fee se lopin ose to m bo yi, ki ni e le so nipa, bawo lo se bere?
ADEIFA: Ayeye odun ifa ti mo fee se yi, kii se emi ni mo daa sile, mo jogunba lowo baba mi ni, mi o si fee ko parun. Pataki e ni lati fi dupe lowo awon orisa ati Olodumare. Awon eeyan ninu ijo nigba miran maa so pe kawon eeyan ba ohun dupe, a a si gbe orisirisi nkan to ba wu lo si soosi tabi mosalasi lati lo fi dupe, iru e naa ni eyi ti mo n se yi. O loju eni to mo pe akoko ojo ibi mi ni mo n se odun ifa yi, mo si fi n dupe lowo Olodumare ni.

AWIKONKO: Ki ni e fe ko je gege bi amoran fawon eeyan paapaa awon ti won ti pa isese ti?
ADEIFA: Won ni ti oyin ba gbagbe ile, kii loro mo, odo to ba gbagbe orisun kii san, isese kii se esin ti eeyan le gbagbe. A o le fi ipa mu enikeni lati se isese, sugbon a o gbodo gbagbe e. Opo awon eeyan ti won o tii je nkan to ye ki won je lo je pe nitori pe won o tii se isese ni ona won ko tii la. Opo lo n sise onise, awon kan wa to je pe isese ni liana won ba lo, sugbon ti won o yasi. Bi a ba wo akosejaye omo, esin ti ifa ba ti so pe ko sin la maa so. Ifa maa n so nigba miran pe ki omo babalawo maa lo si soosi, tabi ko je pe ise babalawo ni omo alaafa maa se, bi ifa ba se gbe e wa ni. A si n ro ijoba apapo bayii ni pe ki won soo di abadofin fun wa. Ipinle Osun ti bere e, won ti ya ojo naa sile fun wa, ijoba apapo la n reti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI