MFM Abeokuta yan igbimo igbeyawo tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

MFM Abeokuta yan igbimo igbeyawo tuntun


Ijo Ori-Oke Ina ati Ise Iyanu, iyen Mountain of Fire and Miracles Ministries, S/W Region 1 headquarters, Abeokuta ti yan igbimo igbeyawo eleni mesan titun ti won yoo maa sakoso eto igbeyawo to ba fee waye ninu ijo naa.

Awon oloye egbe tuntun

Lojo Aiku Sande to lo lohun ni eto ifilole awon igbimo yi waye ninu ijo naa to wa adojuko papa isere Muda Lawal, Asero Abeokuta, eyi ti won tun fi se idupe fun Pasito Ayo Owolabi ti won gbe wa fun won fun ti awon oluso agutan ti won yi pepe po, iyen Pulpit Rotation olosu kan to maa n waye ninu ijo naa kaakiri agbaye lodoodun.

Awon mesan naa ni Pasito Sunday Aderibigbe, Pasito Sunday Akinbola, Pasito Samuel Emuelosi, Pasito Olaniyi Gabriel, Pasito Omoniyi Omowale, Pasito Idowu Adepeju, Arabinrin Olugbemi Oluwafunmilayo, Arabinrin Oluremi Adejumoke ati Arabinrin Kuye toun ti lo fun ise iranse ti won yan an fun.

Alaga igbimo igbeyawo fun ijo MFM lagbaye, Pasito S.A Laoye nigba to n fi awon eeyan naa han ijo lojo naa so pe kii se pe awon kan mu awon eeyan naa lasan, tawon si fi won je oye yi, bi ko se pe won ti la orisirisi idanileko koja, ti won si tun peregede ninu idanwo ti won se fun won. O ni oun gbogbo lo ni eto ati liana ninu ijo MFM, eyi ti igbeyawo je okan pataki tawon ko gbodo fowo yepere mu.

Eyi lo fa ti won fi seto lati maa yan awon igbimo ti yoo maa sakoso igbeyawo to ba fe e waye. O ni leyin ti okunrin ba ti ri obinrin to ba wu, awon igbimo yi ni won yoo seto to ye lati je kawon mejeeji ye lati segbeyawo.

Gege bi IROYIN OWURO se gbo, ni nnkan bi odun meta seyin ni won ti koko yan awon igbimo igbeyawo kan leyin ti ajo to n ri si igbeyawo lorileede Naijiria ti fun won niwe ase l’Abuja lati maa tesiwaju nipa sise igbeyawo ninu ijo, sugbon leyin ti won rii pe ijo naa ti n dagba sii pelu awon ijo tuntun ti won n da sile, lo je ki won tu won ka nitori ninu awon ti won yan nigba naa ni won ti fi da ijo miran sile labe MFM Asero.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI