Opo ojo lo ti ro - Segun Okeowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 25, 2017

Opo ojo lo ti ro - Segun Okeowo

Looto lo je pe irin ajo ogun odun kii se keremi nitori pe ko si bi a se le rin, ki ori ma mi sotun tabi sosi, laarin ogun odun naa, opo adojuko tabi ipenija ni eda yoo ba pade loju ona lati serere.
 
OluwatiiSegun Okeowo
Bi a ba fi gbogbo oni Ojobo Tosde, ojo karundinlogbon ki eeyan wa pataki, okan lara awon gbajumo oniroyin ati sorosoro to sese n dide bo nipinle paapaa lorileede Naijiria, eni to filu Abeokuta sebugbe, o to be, o jo bee lo nitori pe yinni-yinni keni o semi loro naa ri.

Bi e ba pee ni sorosoro tabi akoroyin tabi AyanSegun, bo si je Buloga (blogger) le pe e, eni kan soso le n ke si. Ko seni meji ti a n so bi ko se OluwatiiSegun OkeOwo OluwaPelumi topo mo si Mr Endowed, eni to sese pe ogun odun loke eepe.

Oni gan-gan lojo ibi e, opo awon eeyan lo si ti bere sii ki lati ose to koja ku ipalemo ojo ibi, titi di akoko ti a fi n ko iroyin, teyin naa si n ka bayii ni won si n fi ateranse orifoonu ranse si.

Kii se ateranse ori aago nikan lawon eeyan fi n ranse sii lati ki, bawon ololufe e se n ki lori ero ayelujara Facebook, Twitter, Instagram, 2go, bee ni won tun n pe e lati gbo ohun e, ti won si n kii pe Api baide.

Iyalenu lo je pe OluwatiiSegun ti kii fibe wo aso Ankara lo je pe aso naa lo wo loni ojo ibi e, tawon eeyan si n beere lowo e pe se owo epo wa ni, nibo lo fi eto ayeye naa si.

AWIKONKO gbo pe ojo Aiku Sande to m bo yi ni odomokunrin OluwatiiSegun yi, to tun n ko eko nipa ise eto iroyin ati igbohunsafefe nile eko giga gbogbonise ti Moshood Abiola to wa ni Ojere nilu Abeokuta fi eto ayeye naa si gbongan ile itura Daktad to wa ni Quarry nilu Abeokuta, nibi ti weje wemu yoo ti sele.

Ayansegun
Bee la tun gbo pe opo awon omoge to je ore e lodomokunrin naa ti so fun labele pe ki won wa ye oun si lojo naa, atipe oun ko pe ero pupo nitori eto oro aje orileede yi to mehe, ti ko si fibee si owo repete lowo oun, sugbon lati fi mo riri ise Oluwa ninu aye oun ni.

Bakanna la gbo pe okan lara awon ore e, to tun je bi egbon fun odomokunrin ayangalu yi, Babatunde Popoola tawon eeyan tun mo si Popson ni won jo n gbero pati naa.

Nigba toun naa n ba AWIKONKO soro lori awon adojuko ati ipenija to ti la koja, o so pe melo loun fee so, melo loun fee ka, sugbon Olorun Oba nikan loun le fi ope ati iyin fun, fun ti oore ofe ati anfaani to n ri gba lowo Eleda e lojoojumo.

OluwatiiSegun so pe bo tile je pe ona si jin, atipe oun sese bere igbesi aye tuntun ni, sibe oun ko le salai ma dupe lowo Kabiyesi to fun oun ni emi gigun, ati ibi ti Oba Oke n mu oun lo.

O wa lo akoko naa lati dupe lowo awon obi, ore, atawon ololufee fun ti awon ateranse ti won fi n ranse soun, atawon to n pe atawon to n ki oun lori Facebook.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI