Won ti yan adele giwa fun FUNAAB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 25, 2017

Won ti yan adele giwa fun FUNAAB

Ile eko giga fasiti ogbin tilu Abeokuta, Federal University of Agriculture Abeokuta ti yan adele giwa ti yoo maa sakoso gbogbo eto ile eko naa lati ibi ti giwa tele Ojogbon Olusola Oyewole ba ise de, titi digba ti won yoo fi yan giwa tuntun.

Giwa titun, Enikuomehin
Gege bi a se gbo, Ojogbon Ololade Enikuomehin to je okan lara awon ojogbon ni eka ikekoo ise ogbin ati bi a se n daabobo eso ogbin, iyen Plant Pathology and Mycology, Crop Protection leni ti won fun niwe ase bayii.

Ojoru Wesde to koja yi ni won gbe opa ase fun Ojogbon Enikuomehin nigba ti asiko Ojogbon Oyewole tan lojo Isegun Tusde to koja. Awon alakoso ile eko naa lo gbe ayeye eto naa kale ninu ogba ile eko naa to wa ni Alabata nilu Abeokuta.

Nigba to n soro, akowe igbimo isakoso ile eko naa, Ogbeni Matthew Ayoola so pe ile igbimo asofin ile eko naa lo bu owo lu Ojogbon Enikuomehin gege bi adele giwa tuntun, ti yoo si bere ise e loni pereu lojo kerinlelogun osu yi, iyen ojo naa.

Oga agba pata nile eko naa, Dokita Aboki Zhawa gbosuba kare fun giwa tele, Ojogbon Oyewole fun ipa to ko lati mu idagbasoke ati itesiwaju ba ile eko naa lasiko to fi wa gege bi giwa.

Ojogbon Oyewole nigba toun naa n gbe opa ase sile lo ti fi imoriri e han sawon amugbalegbe to baa sise fun bi won se fowosowopo pelu e lasiko to fi wa pelu won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI