Oro beyin yo; Amosun da awon oga agba OGBC ati OGTV duro nitori iyanselodi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 10, 2017

Oro beyin yo; Amosun da awon oga agba OGBC ati OGTV duro nitori iyanselodi


Kani awon osise ileese redio ipinle Ogun, OGBC mo pe ibi ti oro naa maa ja si niyen, bo ya won ki ba tun ti gba ona miran yo si ijoba ipinle Ogun lori iyanselodi olojo gbogboro ti won gun le laaro oni, Ojoru Wesde.

Gomina Amosun
Ni nnkan bi aago marun un owuro yi ni AWIKONKO gbo pe awon osise ileese redio OGBC ti ji de ofiisi pelu kokoro nla ti won si fi ti gbogbo enu ona aba wole sinu ileese redio naa, eyi ti won tun so pe oga agba pata nibe ko ri aaye lati wole, depodepo pe won yoo sise.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti wa da awon oga agba ileese redio ati telifisan ipinle Ogun, iyen OGBC ati OGTV duro lori iyanselodi naa. Ohun ti a gbo pe o fa idaduro yi ko ju ti suuru tijoba so pe kawon eeyan naa ni lo, to si je pe se ni won so pe iro ni Gomina npa, ko ni nnkan se.

Onimoero Tunde Awolana to je oga agba ileese OGBC ati Onimoero Dele Bolujoko to je oga agba ileese telifisan OGTV ni a gbo pe Amosun da duro, to si je pe se lo so pe oun feyin won ti ni tipatipa, ki won lo mu leta ifeyintin won wa ni kopekope.

Ase yi to gba enu olori awon osise nipinle Ogun, Ogbeni Abayomi Sobande jade ni nnkan bi aago mefa irole oni Wesde so pe ki won bere ifeyinti won lesekese pelu idupe wipe won ku ise takuntakun fun akitiyan won nipa mimu idagbasoke baa won ileese igbohunsafefe ati amohunmaworan ipinle Ogun.

Bo tile je pe ohun ti olori awon osise ti koko so laaro nipe oun yoo ba Gomina sori lori iyanselodi naa, toun yoo si jabo fun won leyin toun ba ti ba Amosun soro tan, sugbon ohun to seni laanu ni pe iroyin idaduro awon oga agba ileese mejeeji lo mu wa fun won.

Ohun tawon kan n so nipe iwa ti Gomina Amosun hu yi ku die kaato, ko ye ko se bee, won ni se lo dabi eni pe o fi owo ola gba won loju ni, nitori pe asiko tawon eeyan naa yoo feyinti ko tii to.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI