Awon adigunjale merin towo olopa te ni Sagamu ti n ka boroboro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 10, 2017

Awon adigunjale merin towo olopa te ni Sagamu ti n ka boroboro

Maa jewo, maa jewo” lariwo ti tawon ogbontarigi adigunjale tileese olopaa ipinle Ogun rowo to lojo kefa osu yi n pa lago olopa leyin towo palaba won ti segi lakoko ti won n sise won gege bi won se maa n se e. Sagamu lowo si ti te won.


Sulaiman atawon ore e

Sulaiman Fatai, eni odun mokanlelogun; Ayobami Alao, eni odun mokanlelogun; Yusuf Sodiq, eni ogun odun ati Emmanuel Adeleke toun je eni odun mejidinlogun la gbo pe Osodi l’Ekoo ni won ti maa n wa digunjale ni Sagamu ko too dipe isu dile leyin asunsu je won.

AWIKONKO gbo pe ni ale ojo towo awon olopaa Sagamu te won, won ti setan lati ja moto gba lowo awon to ba ko si pampe won, sugbon awon eeyan kan to fura si won lo te awon olopaa laago wipe ki won tete maa bo.

Gege bi AWIKONKO se gbo nipa bawon eeyan naa se maa sise ibi won lagbegbe Interchange to wa ni opopona Sagamu, won ni kii se moto nikan ni won maa n ja gba lowo awon eeyan, bi ko se pe okada, owo ati dukia ni won maa ja gba, ti won si n pa awon eeyan lekun.

Won lopo emi lo ti towo won bo lakoko ti won ba n sise won. Bee la tun gbo pe se ni won maa n se bi agbero, to si je pe onimoto to ba duro pe oun fee gbero lodo won ti wo gau, ati pe won tun maa n se bi eni to n toro owo, awon to ba si duro lati saanu ti rugi oyin, gbogbo eru owo onitohun ni won maa gba patapata, ti won a si so iru eni bee si kolobo aye.
Nigba tawon naa n jeri sii, Sulaiman so pe o ti pe tawon ti n jale yi, atipe airikansekan lo sun awon de be, o ni Eko lawon ti maa n wa jale ni Interchange yen, o tesiwaju pea won olopaa ti fee mu awon lojo kan ri sugbon, ori lo ko awon yo, lai mo pe owo si maa te awon.

Nigba toun naa n soro, Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe odaran paraku lawon eeyan naa nitori pe opo awon araalu ni won ti pa lekun, ti won si tun ti demi awon mi in legbodo.

O ni opelope aawon araalu to ta DPO Sagamu, Ogbeni Moses Aduroja lolobo, ko too ko awon olopaa e leyin lati lo koju won. Gege bo se so pe orisirisi eroja oloro bii irin tawon kafinta ma n lo, iyen sisu; ada, obe, pana, lebe atawon nnkan ija oloro miran toun ko le ka tan. O tun so siwaju pe Komisana awon ti pase pe kawon olopaa digboluja, FSARS ko won lo lati tubo lo foro wa won lenu won, atipe ko ni pe ti won yoo foju bale ejo.

O wa fi kun oro e pe, Komisana si duro lori ileri e pe oun ko nii faaye sile gba awon odaran, tabi awon to ba fee da alaafia awon araalu laamu nitori pe aabo emi ati dukia awon eeyan ipinle Ogun lo je oun logun ju, toun si fe kawon araalu maa sun asundokan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI