Shakiru atawon nnkan ti won ka mo lowo |
Won ni kii se pe
Shakirudeen n digungbale nikan, bi ko se pe o tun maa n se ise omo onile lati
gbowo lowo awon to ba ko si panpe e.
Nigba towo palaba e
segi lawon toro naa soju e bere sii so orisirisi pe kii se akoko to ti n sise
naa niyen, won ni o ti pe to ti n sise ibi naa.
Bakanna ni AWIKONKO
tun gbo pe opo emi lo ti towo Shakirudeen bo lori oro ile nitori pe ko le se ko
ma gbe ibon rin to ba ti fee lo dawon eeyan lowo ko lori ile ti won ba ti n
sise.
Lojo tasiri e tu sawon
olopaa lowo yii, won lo o ti gba owo to to egberun lona mejidinlaadorun (#87,600)
naira lowo awon to lo hale mo, ko too dipe won sin eni naa ni gbere ipako pe ko
foro naa to awon olopaa leti.
Loju ese ni won ni eni
naa ti te awon olopaa laago, ti DPO Tijani Muhammad si lewaju awon olopaa to lo
koju oun atawon emewa e lojo naa.
Won ni bawon olopaa se
debe lawon ti Shakirudeen ko leyin ti na papa bora, sugbon toun duro pe ko si
nkan tawon olopaa naa fee se foun nitori pe ile ebi oun ni.
AWIKONKO gbo pe fun
bii wakati kan aabo ni won fi fa oro naa ko too dipe won sakiyesi ibon lowo e,
eyi ni won loo bi awon olopaa naa ninu ti won fi wo sinu oko won, ti won si gbe
e lo si tesan won.
Agbenuso fun ileese
olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa nijeta, iyen lojo
Aiku Sande to koja yi lo ti so pe gbara ti Komisana won, Ahmed Iliyasu ti gbo
lo ti pase pe ki won tete maa gbe odaran naa bo wa si Eleweran.
Abimbola ni orisirisi
ibon akotamin mefa pelu ota ibon to to marundinlogorin atawon oogun abenugongo
to fi n sise buruku naa ni won ri gba lowo e leyin ti won mu.
Iliyasu ti waa pase pe
ki won si tesiwaju lati wadi Shakirudeen ki o baa le jewo ibi tawon elegbe e
toku wa. O wa seleri pe Shakirudeen ko nii pe foju bale ejo labe ofin to tako
iwa ajagungbale nipinle Ogun.
Bakanna lo tun sekilo
pe kawon ajagungbale toku tete fi ipinle Ogun sile nitori pe ileese olopaa ko
tii setan lati faaye sile fun iwa odaran, paapaa iwa ajagungbale.
No comments:
Post a Comment