Owo te adigunjale kan to n yo won lenu ni Ijeja Obada - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 3, 2017

Owo te adigunjale kan to n yo won lenu ni Ijeja Obada

Inu iberubojo lawon eeyan agbegbe Obada Ijeja nipinle Ogun wa bayii nitori bawon adigunjale ko se fi won lokanbale ti won si n ko won sinu ipaya ojoojumo.

Bo tile je pe lojo Aiku Sannde to koja lowo te okan lara awon eni
ibi ohun sibe okan won ko tii bale rara.

Gege bi a se gbo, ni nnkan bii aago mewaa aaro lowo te Odomokunrin kan ti won pe oruko e ni Kehinde Adebiyi tinagije e n je Shadow Enuose lakoko toun ati keji e, toun je Toheeb tiyen ti salo loo fo okan lara ile to wa ni Obada Ijeja naa.

Won ni Toheeb lo wa ninu ile to pitu, nigba ti Kehinde towo te wa nita, nibi to ti n sona, sugbon nigba ti owo palaba won maa segi, leyin ti won ja oju ferese ti won gba wole tan, ni won enikan rin sakoko, ti won si fese fee.

AWIKONKO gbo pe nibi ti won ti sa  lo, lawon ara adugbo ti dena de won, ti won si woya ija peluu won,obe ti won lo wa lowo Toheeb lawon eeyan naa beru, nigba to fee fi gun won, to si fir aye salo, sugbon ti won mu Kehinde mole ni tie.

Loju ese la si gbo pe awon odo adugbo naa ti de adigunjale towo te naa mole bi eran, ko to dip e won luu bi eni maa ku,leyin wakati meji towo ti te ni Iya e atoko egbon yoju ti won si wa bebe.

Sugbon gbogbo ebe won pabo lo ja si, nitori se ni won muu loo si tesan awon olopaa to wa ni Adigbe.

Ise alapata iyen awon ton teran ni Kehinde so pe oun se, sugbon  omo Itoko lo pe ara e, awijare to kan tenu mon on nip e Toheeb to salo lo ni koun si oun jade, bawon si se de Obada ni igbe gbon oun, oun ko mo pe ole lo wa ja.

Ninu oro Oloye Folorunso Bodunrin to je Baale agbegbe ti won ti jale naa, o so pe kii se igba akoko ree tawon adigunjale yoo ti maa ko ipaya bawon, o ni aimoye igba ni won si ti wa ti won wa pawon eeyan lekun.

O so pe bii eemeji otooto lowo awon tite awon adigunjale lagbegbe won, to je pe awon maa n gbe won dele ejo, ko to dip e awon pada leyin won. O ni aifimosokan lo je wahala awon ladugbo, oun lo si je ki eto abo won mehe.

Okunrin yii ati alaga agbegbe naa war o ijoba lati ran won lowo, ki won ba won pese eto abo, bee ni ki won gbawon ninu okunkun biribiri ti won n gbe, won niyen lo je kawon ole naa maa raye.

Ni bayii, Agbenuso awon olopaa nipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe loju ese lawon yoo gbe kehinde towo te  naa loo sile ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI