Paseda seleri ile egbe fegbe FUMAN ipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Paseda seleri ile egbe fegbe FUMAN ipinle Ogun

Bee ni Malaika foju tembelu e

Lojoru Wesde ose to koja ni egbe Fuji Musician Association of Naijiria, FUMAN, eka tipinle Ogun se ibura fawon oloye titun fegbe naa ni gbogan to wa ninu ogba Olumo, ladugbo Ikija Abeokuta.

Paseda ati Malaika lakoko ti won pade
Nibi eto naa ni won ti fi iwe pe Otunba Olarotimi Paseda to je okan lara awon oludije sipo gomina nipinle Ogun lati wa ye won si gege bi alaga ayeye eto ibura naa.

Sugbon nigba ti Otunba Paseda n soro lo ti so pe ninu awon nnkan ti a fi n gbe asa ati ise laruge nile Yoruba, orin kiko, paapaa orin Fuji je okan pataki, ti ko si see  fowo yepere mu, nitori e loun se feran Fuji, toun ko le se lati ma gbo.

Leyin ti Paseda n kadi oro e nile, o so pe bi oun ba wole gege bi Gomina ipinle Ogun lodun 2019, ki won wa lati wa ran oun leti wipe oun seleri ile nla fun won, eyi ti won yoo maa lo lati maa sere, tawon ololufee won yoo si wa maa woran won. Bee lo tun fun won ni egberun lona igba le ni aadota naira, iyen 250,000naira.

Paseda ati Malaika leyin ti won pade
Bi Otunba Paseda se soro tan ni alaga egbe naa nipinle so fun un pe, okan lara awon agba to tun je irawo olorin nipinle Ogun, iyen Alaaji Sule Adio Malaika naa n ya ise e kan lowo loke Olumo, ko wa lo o ki lori oke.

Bo se ku die ki Paseda de odo Malaika, ni won so fun un pe Paseda lo n bo yen, ko lo pade e, sugbon n kan to so nipe talo n je be, talo mo o ri, lati ibo, sugbon lara awon agba egbe naa lo so pe okan lara awon oludije to n lewaju fun ipo gomina ipinle Ogun, ko too di pe, o ni ki won je ko wa ba oun nibi toun wa.

Bo tile je pe Paseda ko mo nnkan to n sele nitori pea won ero ti wa niwaju e, sugbon nigba to de odo Malaika, se lo ki daadaa bi eni pe won ti mo ara ri tele, to si so pe oun maa n gbadun awon orin e, toun naa si kii pe ose.

Awon toro naa soju e lo so pe iwa ti Malaika hu lojo naa ku die kaato, nitori pe iwa igberaga ni, atipe ko ye ko se be. Bakanna la tun gbo pe fun bii wakati meje ti Malaika lo ninu ogba Olumo yi, ko fi iseju kan yoju sibi ayeye ibura fawon oloye egbe tuntun naa, se ni won ni o da won nu bi omi isanwo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI