Owo te awon omo egbe okunkun mokanla ni Alagbado - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Owo te awon omo egbe okunkun mokanla ni Alagbado


Ileese olopa ipinle Ogun ti rowo to mokanla lara awon omo egbe okunkun ti won lo n da ipinle Ogun laamu, eyi ti won lobinrin meta wa laarin won. Adugbo kan ti won pe ni Ijeja nilu Alagbado ni won lasiri won ti tu sawon olopaa lowo lojo Aiku Sande to koja lakoko ti won ni won n gbiyanju lati da wahala nla sile lagbegbe naa.

Awon omo egbe okunkun naa
 Awon mokanla naa ni Abayomi Agbefolaju, eni odun meedogbon; Alaba Ayoade, eni odun metadinlogun; Olamide Abdul Rasheed, eni odun mokanlelogun; Hakeem Ayoola, eni odun mokanlelogun; Olaoye Gbolahan, eni odun mokanlelogun; Adebayo Julius, eni odun mokanlelogun; Taiwo Sodiq, eni odun mejilelogun; Teniola Imoleayo, eni odun mejilelogun; Adesina Aminat, toun je ogun odun; Seun Odemuyiwa, eni odun mejidinlogun ati Kehinde Adunoye toun naa je eni odun mejidinlogun.

Eru ti won gba lowo won
Alukoro olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro naa fawon akoroyin so pe bo tile je pe ada pana, lebe, fila bulu, aake, oogun, atawon eroja oloro orisirisi lawon ri gba lowo won, sugbon Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won tare won lo si odo ajo SCIID lati tesiwaju ninu ise iwadi.

Iliyasu so pe ipinle Ogun ko ni faaye gba iwa ibaje paapaa iwa odaran bii ti egbe okunkun, nitori naa kawon obi atawon alagbato lo towo omo won bo aso.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI