Gbajumo
olorin fuji nni, Ogbeni Wale Thompson topo mo si Misita Lalale Fraide ti gbe
orin titun jade bayii leyin opolopo odun tokunrin naa ti korin gbeyin latari
ijamba oko kan to ku die ko gbemi e.
Gege
bi AWIKONKO se gbo, Chop My Life lakole orin titun ti Wale Thompson gbe jade,
tawon eeyan paapaa awon ololufe e to n gbo orin naa si n kan saara sii pe orin
si n be lara e gidi gan.
Ileese
to n gbe orin jade ti won pe ni Godfather Music lo gbe orin naa jade, topo awon
eeyan lorisirisi si ti n gbe osuba kare fookunrin naa pe ise lo se.
Bi
e o ba gbagbe, Lalale Fraide lorin to gbe Wale Thompson sita faraye tawon
ojogbon nigba naa si so pe oun loba awon olorin juju latari awon alujo ati
takasufe to fi kun un.
No comments:
Post a Comment