Fi ipo Aare sile bi o ba feran Naijiria – Fayose so fun Buhari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 31, 2017

Fi ipo Aare sile bi o ba feran Naijiria – Fayose so fun Buhari

Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele fayose ti gba Aare orileede yi, Ogagun Muhammadu Buhari lamoran pe ko kowe fipo sile gege bi Aare bo ba mo pe oun feran orileede yi tokan-tokan.

Fayose soro yi nilu Eko lojo Isegun Tusde to koja lakoko to n bawon akoroyin soro lori ipo ti orileede Naijiria wa, paapaa isejoba Aare Buhari, pelu ipo ailera to wa.

O so pe gbigbogun ti iwa ajebanu ko da lori sisawari owo rabati ti won n doju ko lo, bi ko se pe ki o se awon nkan to ye lasiko to ba ye.

Bakanna ni Gomina Fayose so pe isejoba Aare Buhari paapaa egbe oselu APC ti kuna laarin odun meji to fi wa nibe, o ni ko si eyi ti won muse ninu awon ileri ti won se fawon omo orileede yi lakoko ipolongo idibo lodun 2015.

O so pe eni ti ara e da saka to le sise losan loru lati koju awon isoro ati ipenija ti orileede yi n koju lasiko taa ni orileede Naijiria nilo lati fi se olori, kii se to je foniku-foladide. O ni igba wo la fee se gbogbo irinajo okeokun da.

Bee lo so pe igbakeji Aare, to tun je adele Aare lowolowo bayii ko lase Kankan to fee pa leyin Aare funra e. Oun gang an lo ye ko so ipo ti ilera ara e wa fun wa, kii se awon amugbalegbe e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI