Won lawon olori ijo sele sowo ijo basubasu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Won lawon olori ijo sele sowo ijo basubasu

Ile ejo ni won wa bayii.

Mobiyina Osofa
Kii se pe oro naa sese bere, won ti wa lenu e tipe sugbon ni bayii, oro naa ti kuro ni bonkele, o si ti jade sita gbangba, awon olori ijo Sele, iyen Celestial Church of Christ, CCC ni won ti gbe ara won lo sile ejo giga to wa ni Ikoyi niluu Eko lori esun sisowo ijo naa basubasu, ti won ko si ni akosile gidi lori bi won se n sowo naa.

Okan lara omo ijo naa, to tun je okan lara igbimo agbagba BOT ninu ijo naa, Alagba John Rotimi Omotosho topo mo si Baba Jorotom lo gbe awon agbaagba ijo naa, ninu eyi ti Olori won patapata, Mobiyina Friday Osoffa wa ninu won peluu awon merin min in, loo si ile ejo giga keje lojobo Tosde ose to koja, nibi ti Onidajo Chuka Austin Obizor ti n gbejo won.

Awon yooku ti won tun jejoo peluu Olori ijo won ni Pius Olanrewaju, Ojogbon Bola Akinterinwa, Ogbeni Segun Aina ati Ogbeni Samson Banjo. Lara awon esun ti won lokunrin naa fi kan won ni sisi iwe banki min in to yato si eyi tijo naa n loo, sisowo ijo naa basubasu lai le so pe bayii lawon se n nawo naa atawon nnkan min in. Bee ni okunrin yii tun ro ile ejo pe ko pase ki awon to fesun kan naa ye kowo bowo ijo naa mo titi ti idajo yoo fi waye.

Baba Jorotom
Nibi igbejo to waye naa ni Adajo ti pase pe oun fun Alagba Samson Banjo lati wa ona ti alaafia yoo fi joba, gege bi oro ti agbejoro won so pe igba merin otooto lawon ti gbe igbese lati yanju oro naa laarin igun mejeeji.

O ni oun fun won laye lati loo lo anfaani naa lati yanju e sugbon ti ko ba seese, to je pe ofo naa ni, a je pe igbejo yoo bere ni pereu. Bakan naa lo tun so pe ki gbogbo nnkan si wa bo se wa laarin igun mejeeji to n ja naa titi ti igbejo yoo fi waye lojo karun osu kefa odun yii.

Bo tile je pe ko too to akoko yii lawon ti Mobiyina Osoffa ti pe Jorotom naa lejo ni kootu giga keta to wa ni Ikoyi nipinle Eko bakanna pe ki okunrin yii wa so bo se se milionu mejile laadosan naira(N172 milionu), ti won lo je lara owo ti won fi n ko Jerusalem tuntun to wa ni Imeko, eyi ti won lo wa ni ikawo e lakoko to fi je alaga igbimo fun kiko ijo tuntun naa, sugbon se ni Onidajo Kaka to n gbejo naa da ejo ti won pe okunrin naa nu, nitori won ni ko lese nile.

Ni bayii, ko seni to le so pato ibi ti ejo naa n loo, nitori bi awon ti Jorotom fesun kan se so pe awon ko jebi, ati pe kii se nnkan to bojumu lati maa gbe olori ijo loo si kootu. Sugbon tawon ti Jerotom so pe o dawon loju pe idajo ododo yoo waye, nitori awon mo pe inu okunkun biribiri lawon ti won fesun kan fi awon omo ijo Sele si, ti Olorun si ti setan lati tu asiri won sita.

Jorotom atawon alagba kan ni Ketu
Atipe Jorotom funra e ti figba kan so pe kii se pe oun fee dupo olori ijo naa tabi pe oun n wa ipo nla ninu Sele loun se n sagbateru lati tu asiri awon to n ba ijo naa loruko je, bi ko se pe alaafia, isokan ati idagbasoke ijo Sele loun n wa, atipe ki ileri Olorun fun ijo naa le wa si imu se nipa fifo aye mo loun fe ko wa si imuse.

O soro naa lojo ajinde to waye ninu ijo Sele, eka e to wa ni Akowonjo, iyen Jerusalem Parish Cathedral, o tun so pe oun ko le fi ejo naa sile lai je pe ile ejo da ejo naa bo se to ati bo se ye nitori pe awon ti Baba Oshoffa ti ba oun naa loruko je pe oun kowo je.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI