Asiri iku to pa Pasito Ajidara re oooooo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Asiri iku to pa Pasito Ajidara re oooooo

Won ni aisan kidirin naa ti le ni odun marun
Awon osere tiata tun soro ile kun

Pasito Ajidara
Ironu iku agba osere tiata nni, Olumide Bakare lo si wa lokan gbogbo eeyan, paapaa awon osere tiata kaakiri orileede Naijiria ati ni oke okun ti ko si tii kase nile ko too di pe ajalu nla miran tun wo agbo tiata wa.

Ibeeere tawon eeyan n beeere ni pe “igba wo ni aisan kidirin naa ti bere, igbawo lawon eeyan to fi mo awon omo egbe e to pariwo sita.” Ohun ti a gbo ni pe kii se pe aisan naa sese de si lara, o ti le ni odun marun, to si ti na opolopo owo le e lori.

Beeyan ba de ile okunrin naa to wa ni Oluwo, Abiola Way niluu Abeokuta, ko digba ti won ba to o so, ki won to mo pe akoni pataki kan lo lawujo, bawon kan se n sunkun, bee lawon min in parowa siyawo ati ebi okunrin naa.

Nigba to wa lori beedi
AWIKONKO gbo pe nirole ojo Eti Fraide, ojo kerin osu yi ni iroyin jade sita pe ara agba gbajumo osere tiata nni, to tun je Gomina fegbe Theatre Arts and Motion Picture Association of Nigeria, TAMPAN, eka tipinle Ogun, Ogbeni Samuel Adesina Adesanya (JP) ko ya, o si nilo iranlowo owo to to milionu meedogun naira, gege bi Yomi Fash-Lanso se gbe e sita, iyen lori ero ayelujare.

Ninu oro ti Fash-Lanso ko sita naa lo ti fi akanti nomba iyawo Pasito Ajidara, Atinuke tawon eleyinju aanu le san owo si pelu e, ti a gbo pe lesekese tawon alaanu ti ri ni won ti n fi owo ranse sinu akanti naa, lati ran Pasito Ajidara lowo, tinu won si n dun pe awon eeyan feran won.

Lakoko tawon TAMPAN lo sabewo si
Laaro ojo Abameta Satide niroyin ti kan kaakiri agbaye, nitori opo iwe iroyin, iroyin ori ero alatagba, ileese telifisan ati redio ni won fi n fonrere pe kawon eeyan ran won lowo lori aisan kidinrin to n yo Pasito Ajidara lenu, to si nilo ki won gbe e lo silu Oyinbo lati se ise abe fun un.

Sugbon nigba to di nnkan bi aago mesan abo ale oj Satide ni oro yiwo, nitori ohun ti a gbo nipe awon osere tiata tegbe TAMPAN si wa lodo e ni nnkan bi aago mejo abo ale ojo lati lo kii, ti won sit un gbadura fun un. Ohun ti won lo n tenumo fun won ni wipe ki won sa gbogbo ipa won lati tete je ki fiimu ti won n ya loruko egbe TAMPAN tete jade sita ko too pe ju.

Won ni ko tii ju bi iseju melo kan lo tawon egbe TAMPAN kuro lodo e loro beyin yo, tawon noosi, dokita atawon toro naa soju e bere sii forigbari, ti won n sare soke-sodo lati doola emi, nitori ti won so pe bi Ajidara se n mi ti yato si ti tele, eyi ti won lo o ko iberubojo bawon eeyan lojo naa.

Ile Pasito Ajidara
Lesekese ni won ti gbe ero agbemiro (oxygen) si lara pe ki ara e le fi bale, sugbon fun bii wakati meji, se ni iku n ba a jijakadi naa karakara, ko too di pe Pasito Ajidara gba fun elemin, to si ku ni nnkan bi aago mokanla koja iseju meedogun.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ohun ti won loo je ki iku Pasito Ajidara ya ni Kankan ni ti iroyin to gbo pe o n lo kaakiri igboro pe kawon omo Naijiria ran oun lowo, eyi ti won so pe o je pataki nnkan ti ko fe laye. Ko fe ki won toro owo foun nitori aisan to n se oun. Bo se gbo oro naa lo ba wo o pe, ohun ko le la oju oun sile ki won ba oun loruko je.

Opo awon eeyan ni won ba AWIKONKO soro lori iku to pa Oloogbe Samuel Adesina Adesanya, topo mo si Pasito Ajidara, eni to je pe kekere lo bere ise tiata, ko too darapo mo ile ise eto idajo nipinle Ogun, to si feyinti ni lodun 2015 leyin odun marundinlogoji tawon osise ijoba maa n lo lenu ise.

Ironu dori agba kodo
Titi di aaro ojo Sande lawon eeyan ti won ko gbo pe okunrin naa ti jade laye si fi n fowo ranse sinu akanti iyawo e, tobinrin naa si so fawon to n sagbateru ikede iranlowo naa pe ki won so fawon eeyan pe ki ma se fowo ranse mo, nitori pe eni ti won n tori e fowo ranse ti papoda, o ti dagbare faye.

Ki Pasito Ajidara too feyinti lo ti je alaga nile ise eto idajo ipinle Ogun, to si daadaa lakoko to fi je alaga nibe.

Lesekese ti iroyin ti te Yomi Fash-Lanso leti lo tun ti sare se fidio oniseju kan lati fi kede pe Pasito Ajidara ti ku, tawon eeyan si ti bere sii foro ibanikedun ranse sawon ebi e lati ori ero ayelujara naa.

Osibitu kan ti won pe oruko e ni Mercy, to wa ni adugbo Panseke, Abeokuta lokunrin naa ku si, sugbon ko to di pe o ku lo ti maa n lo se ayewo lori aisan naa, ti won lo si ti na opolopo owo ara e le lori. Won ni okunrin osere yii je enikan ti ko feran lati maa bebe fun owo, to si je eni to ko ara e nijanu.

Ka ni bi aisan naa se wa lara e lo ti pariwo sita fun iranlowo owo fun ise abe ni oke okun ni, o seese ko si wa laye titi di akoko yii sugbon nitori o je enikan ti ko fee iwosi, ti ko si feran ki won maa pariwo ara e kiri.

Bi iroyin Pasito Ajidara se kan sita
Oku Ajidara
AWIKONKO gbo pe, lojoru Wesde ose to koja, tawon omo egbe onitiata TAMPAN ti Ajidara je gege bi Gomina won fee se ipade ti won maa n se losoosu, ti won ko ri ko yoju, lawon kan ninu won to mo pe ara okunrin naa ko ya, bo tile je pe ko je ajoji sawon kan.

Loju ese ti won si pari ipade lawon oloye egbe naa loo yoju si ni osibitu Mercy to wa, ti won si so abo ipade naa fun won, sugbon siyalenu opo won, nigba ti yoo fi di ale ojo Eti Fraide won ti gbe soro ero ayelujara pe aisan kidirin n yo gbajumo osere tiata naa lenu, won si nilo owo lati gbe loo si oke okun.

Nigba ti yoo si fi di aago mefa idaji aaro Sannde, okiki ti tan kaakiri pe Pasito Ajidara ti ku, opo awon osere ti won gbo ti pejupese si osibitu Mercy ti okunrin naa dake si, nibe ni won si ti gboku e loo sile igbokusi to wa ni osibitu Jenera, Ijaye niluu Abeokuta.


Awon omo Ajidara soro nipa Baba won

Arabinrin Ogunsina Adedayo Adeshina (nee Adesanya)
Adedayo
Emi ni akobi won, emi gan ni mo le so pe mo je aayo baba mi, ti mo fi ara ro won ju nitori pe ko le se ko ma pe mi to si maaa ba mi dapara lori foonu. Gbogbo eeyan lo maa n pe mi ni omo baba e. Nkan ti mo le maa fi ranti won po repete, se ti oro baba s’omo ti won maa n ba mi so ni abi ti awon oro itunu, bi a se le lo ile aye lona ti yoo rorun. Oro bi a ko gbodo se kanju wa owo nitori baba mi gbagbo pe atelewo eni kii tanni je. Awon ona naa la si ti n tele gege bi omo.

Ile ni mo wa nigba ti won dake nitori mo wa wo omo mi atawon aburo mi kan nile, lesekese naa ni mo ti wa ona lati debe ni nnkan bi aago mejila.
Awokose ti mo ri ko lara won ni pe baba mi kii wo aago alaago sise, o si maa n tele ilana ofin, temi naa si n ti n tele nitori pe a jo sise nibi kanna an ni.

Adesanya Adedamilare Oluwaseyi
Oluwadamilare
Oro a po ti n ba ni ki n so bi won se je si mi, sugbon nitori pe emi ati won kii se oloro pupo ni ko je kawon eeyan mo pe mo nife won. Emi o feran lati maa soro pupo bii ti won, nitori pe awon feran oro pupo gege bi ise ti won n se. opo eko ni mo ko lara baba mi ko too jade laye.

Mo wa legbe beedi won losibitu ki won too jade laye lale ojo naa. Won ti n je irora yen lati bii ojo merin, ti ale ojo satide yen tun le ju, to je pe aya gbogbo wa lo ja, sugbon ohun gbogbo ye Olorun Oba. Ni nnkan bi aago mejo abo ale ni mo gbe egbon mi wa sile, igba ti mo pada debe ni mo rii pe won ti gbe ero agbemiro (oxygen) si won lara, nibe lokan mi ti n so pe nnkan fee sele, sugbon a dupe lowo Olorun.
Eko ti mo ri ko lara baba mi po nitori pe o je alakitiyan eeyan, oro amoran lorisirisi.


EYI LORO TAWON OSERE TIATA SO NIPA PASITO AJIDARA 

Inu ijamba oko ni aisan kidirin ti de si Pasito Ajidara - Tajudeen Edun topo mo si Mogaji tabi Olori Ebi
Olori Ebi
 Oga mi ni Pasito Ajidara lenu ise ijoba, o je eni to fa mi mora gan an ti mo si rii pe gbogbo nkan ti mo n fe ni mo n ri lara e, lo se je ki n mu gege bi baba. E o le gba ti won ba so fun un yin pe mi o kii n se ebi won nitori bi a se sunmo ara to. A ti wonu ara wa ju bawon eeyan se lero lo.
Nidi ise tiata, mo le so pe oga mi ni, mo tun le so pe oga mi ko nitori pe ti a ba ni ka wo, agbalagba ni, igba tawon n sere ti won, ere oloyinbo ni, tawa naa si n se ti wa ni Yoruba.
O pe ko too di pe a pade eyi lo je ki a mo pe omo Yoruba kanna an ni wa, ti a si nife ara wa gidi latigba naa. Asiwaju rere to see fi yangan ni, nitori pe titi to fi ku la fi jo rira. Ni gbogbo ona ni mo maa fi maa ranti oga mi, se lori irin ni ki n so ni tabi lenu ise. Pasito Ajidara ni alaga ile ise eto idajo ti a ti n sise ko too di pe won feyinti. Nigba ti won si fee feyintin won lo gbogbo agbara ati ipo won lati rii pe emi ni mo di alaga naa nitori pe idibo ni won fi gbe mi wole.

Won o bi aisan kindinrin yi mo Pasito Ajidara, sugbon ni odun 2012 nigba ti won wa lenu ise ni kootu majiisireeti to wa ni Owode, Sagamu lemi wa nigba naa, owode  ni won ti n bo loo sile won ni ijamba oko to je pe se ni moto yen pare tan, Olorun lo yo won ninu e. Ijamba yi lo sokunfa kidirin won to n se segesege latigba yen, to si je pe won ko le se ki won maa lo sile iwosan lati lo sayewo.

Leyin opolopo osu ni won too bere sii to daadaa, sugbon nigbati aisan to mu won lo yi maa fi de, se la gba pe asiko Olorun ti to ni. O je alakikanju eeyan to maa n sa gbogbo agbara e lati se nnkan.


Owo mi ni Yomi Fash-Lanso ti gba foto to gbe sori ero alatagba - Adeleke Adetutu topo mo si Seyi Crown, Alukoro fegbe TAMPAN nipinle Ogun.
Seyi Crown
Gbogbo bi won se n gbe won kaakiri la n tele won. Nigba ti won gbe won kuro ni osibitu FMC lo si osibitu kan lona OGTV. FMC yen la sese too mo pe aisan kidirin ni Pasito Ajidara ni, ati pe ori aisan yi ni won n na gbogbo owo ti won n ri le. Opo ni ko tete mo pe aisan naa ti wo Pasito Ajidara lara to bee yen, afigba ti a de ipade lawon eeyan too mo pe ile iwosan lo wa.

Ki a too bere ipade lojoru Wesde ojo keta osu yi, odo won ni mo wa ti won si so pe mo gbodo wa a jabo fun won lori ipade ti a ba se, won ti e foro ebe ranse pe awon ko ni le yoju, ki igbakeji soju awon nitori pe won ko tii le so igba ti won maa fi won sile.

Won gbiyanju lati dide lati fara han w ape looto lawon ko le dide duro mo, won ni omo awon lo maa n gbe won ti won ba fee yagbe, tabi to.

Ojo Wesde naa ni won yo kaadi won pe ki won maa lo sile. Sugbon lojo Friday to tele ni mo tun pe won pe bawo lara won, nnkan ti won so fun mi ni pe awon fee de osibitu lati lo sayewo, igba yen lara ti n fu mi pe se kii se pe oro yi fee yiwo nitori bi won se n soro lojo yen, ohun won ko ja geere.

Won gbe oku Ajidara lo si Motuari
Ibadan ni mo wa nigba ti Yomi Fash-Lanso pe mi pe ki n fi foto Pasito Ajidara ranse soun, ero okan mi ni pe o fee lo fun ayeye kan to n bo lona ti won fee se ni, lesekese ni mo ti pe won lati fi to won leti.

Ni nnkan bi aago mefa irole ojo Fraide naa ni aburo mi kan pe mi lati Eko pe won ni  Pasito Ajidara nilo owo lati fi sise abe fun ti aisan kidirin, mo beere lowo e pe nibo lo ti ri, o so pe Yomi Fash-Lanso lo ko sori ero alatagba, nigba na ni mo sese war anti pe o ni ki n fi foto ranse laimo pe nnkan to fee fi se niyen, lesekese ni mo ti pe e pe kilode to fi se bee nitori pe oga o fe be, o ni oun ti gba ase lowo Mista Lati ati iyawo e.

Gbogbo igba ti mo wa ni mo n pep e bawo ni ara won,a fi bo se di aago mejila ku ogun iseju ale Satide tiyawo won pe mi, bi won se pe mi ni ara ti fu mi pe nnkan ti sele, ni won ba ni Gomina wa ti ku.

Ajidara je eni to ko iwosi, to si ko ara e nijanu, kii fee kawa omo egbe e maa toro owo kaakiri.Iwa ajafetoo e lo gbe wo ise tiata, to si maa n gba awa omo egbe nimoran, ko gbagbo pe ko si nnkan ti ko seese,beeyan ba ti nigbagbo, to si duro gbingbon.

Mi o le gbagbe owo ounje ti Pasito Ajidara ma n fun mi - Alaaja Olayinnka Adebanjo topo mo si Say Mama
Olayinka Adebanjo
Iku Ajidara to je gomina wa dun wa, to si ba wa lojiji, lakoko ta n gbadun e fawon ise rere to n se ninu egbe, nikuu muu loo. O je enikan ti ko fee ireje, ti ko si feran ka maa toro owo paapaa ninu egbe.

Nkan ti mo si so fenikan laaro yi ni pe boya ironu wipe won gbe sori afefe pe kawon eeyan dawo fun won lati fi sise abe lo tete mu emi e lo nitori nnkan to korira ni. O fun wa ni ATM e pe ki a lo gba owo lati fi pari fiimu egbe ti a n ya lowo

A si jo wa lose to koja nibi ti a ti jo n dapara ni.  Gomina mi kii fe ki ebi pa mi. Mi o le gbagbe igba to maa n fun lowo ounje. Ti m ba pe e pe taya moto mi baje tabi mo nilo owo, o maa ni ki n wa gba owo ni.


Iyawo kan, omo meta ni Pasito Ajidara bi - Ogbeni Adesegun Adesinna Emmanuel
Adesina Emmanuel
O je edun okan fun mi pe asiko yii ni okan lara awon oga to ko mi nise papoda, Oga mi ni won, mo sunmi won gan, won je eni ti kii soju saju. Awon nnkan to le mu ki egbe tesiwaju lo maa n se ti won kii si beru lati soro, won ni igboya gidi gan, ko si kawa omo egbe maa ma ranti won.

Iyawo kan soso ati omo meta ni Pasito Ajidara ni, odun to koja lo se igbeyawo fun akobi e. o see se ko je pe ilu Abeokuta ni won maa sin in si, mi o tii le so. Pasito Ajidara ko tii ju eni odun metale si merinlelogota lo (63-64years).



Olooto Eniyan ni Pasito Ajidara – Oluwagbenga Edun, Alukoro TAMPAN Abeokuta North
Oloogbe Ajidara je olooto eniyan, eni ti ko kii fi okan bo okan ninu, kii fe toro nkan lowo eeyan, o maa n tiju lati toro owo loruko egbe. Ko nife si wipe ki a dawo ninu egbe, ki a wa so pe ka koko yo tawon oloye egbe soto. O nife awa ta n bo leyin, o nife egbe yi dokan, ko sigba ti Pasito Ajidara kii si ni ofiisi laarin ose nitori ife ti won ni si egbe.

Alakikanju eniyan to ni afojusun ati ile pa ni, nitori pe titi ti a fi jo wa ni osibitu ko too di pe o jade laye lo si n tenumo wipe ki a gbiyanju lati je ki fiimu ti a ya loruko egbe tete jade, nitori pe oun ni Gomina akoko ti won maa se fiimu loruko egbe jade labe e.

Akobi, Iyawo, Abigbeyin ati omoomo Ajidara
Ohun ti AWIKONKO tun ri gbo bayii nip e, egbe osere tiata TAMPAN eka tipinle Ogun ti gbe igbimo dide ti yoo sise lori eto isinku agba osere naa. Omooba Bolaji Amusan topo mo si Mista Latin ni won fi se alaga igbimo naa.

Bo tile je pe won ko tii mu ojo ayeye isinku sugbon bi a se n gbo nile oloogbe naa, sugbon o seese ko je pe ojoru Wesde, ojo ketadinlogun si ojo Abameta Satide, ogunjo osu yi ni won fee fi si. Iyen tawon molebi atawon igbimo ti won yan ba jo fimo sokan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI