Bi e ba ri Maanu ti
won n pe ni Omoba yen, Babatunde Abdul-Gafar Okunade nibi to ti n run agbado je, se le maa
koko ro pe aawe ti tan ni, nitori pe ko ti e rii ro pe aawe wa nita rara, bee
Musulumi to gba esin gbo ni.
Alabi Okumase |
Omoba tawon eeyan
tun n pe ni Alabi Okumase to je okan lara awon agba sorosoro FIBAN nipinle Ogun
leni ti AWIKONKO n so yi. Ohun atawon ore e meji kan ni won jo jokoo, ti won n
je agbado sisun naa.
Maanu yi to je pe
odoodun leyin aawe lo maa n se eto kan to pe ni Ijo Islam, to maa fi n gbe esin Islam laruge yi lo ya ni lenu pe ko
gba aawe, bo tile je pe o ma awon atubotan eni ti ko gba aawe gege bi esin naa
ti laa kale.
Alabi Okumase to
sese de lati India nibi to ti lo o se apa e to n dun un yi lo tun n pariwo ebi
n pami pelu agbado to n je lowo, to si je funra e lo lo ra agbado naa. Bo ya ko
ti e mo pe awon eeyan n wo bo se n se ni.
Nibi to ti n je agbado |
Ohun to n so ni pe
beeyan ba ri oun bayii, ko nii mo pe oun si n loogun si apa to n dun oun ni,
won ko nii mo pe apa naa ko tii jina, asiko toun yoo si fi loogun ki apa naa le
tete jina ko tii to.
Ibeere tawon to ri
AbdulGafari nibi to ti n je agbado ni pe se kii se elesin Musulumi mo ni, abi o
ti gbagbe pe aawe si wa nita ni, sugbon se lo fun won pe nnkan to ba wu elenu
lo le fenu e so.
Bo tile je pe
okunrin naa ti n wo soosi bayii, sugbon se e mo awon onise igbohunsafefe, ko
seni ti won ko le ba se, tori pe ise eni lo n towo eni bo epo, awon to si le
gbe ise fun won ni won gbodo maa ba se.
Kii se pe Omoba mon
on mo ma gba aawe ni o, sugbon saa, ilera loro, eeyan ko si gbodo fi ibi to n
dun sabe aso, kii se odun yi nikan ni aawe mo, awon ojo lati gba aawe si guun
lo titi.
Omo olomo ti ko tan ara re,sugbon bi ko ba nidi obirin kii je kumolu.
ReplyDeleteAbi o
ReplyDelete