Haaa! Se ooto ni nkan ti Kasnaty so nipa idibo FIBAN l’Ogun yi sa? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 6, 2017

Haaa! Se ooto ni nkan ti Kasnaty so nipa idibo FIBAN l’Ogun yi sa?

Bo tile je pe lati bi ose meji seyin ti alaga ana fegbe sorosoro FIBAN, eka tipinle Ogun, Ogbeni Akinyemi Olatoye, eni to ti se gudugudu meje ati yaya mefa nipa ilosiwaju egbe naa ti so pe oun ko lo fun ipo alaga naa mo leekeji latari oro alufansa tawon kan n so pe ki loot un fe e lo o se, bo tile je pe okunrin naa ti so pe a fi koun pada nitori awon alafo kan toun ri, toun si fee di pa.

Kasnaty
Eyi lo fa a tegbe naa fi dabi eni pe o pin sona meta nigba tawon kan tele iko Alawiye ti Olufemi Omilani fe e gba jade, iyen eni ti won gbe dide lati tako adije fun ipo alaga naa, Ogbeni Adeyinka Adegbite, Omo Baba Tisa to so pe ipo naa wu oun pupo nigba ti won so pe Alawiye ko tete je kawon eeyan mo ero okan e pe o tun fee lo si.

Gbara ti won ti kede Omilani lati inu egbe ti Alawiye gege bi eni ti yoo tako Omo Baba Tisa toun wa ninu egbe MC Murphy lorin ti bere sii dowe, to si je pe aroko ote lawon eeyan naa n pa ranse si ara won lori redio, tawon kan si da duro lati wo ibi toro naa fee yori si.

Gbogbo won ni won si ti bere sii so ara won lori redio lati gbo nkan tawon alatako won fee so lori eto, bo ya won fee bu eebu, bo tile je pe awon kan ti reke eebu sile pe eni to ba gbemu, awon yoo fimu e danrin ni.

Gege bi AWIKONKO se gbo, okan lara awon omoleyin sorosoro taye n gba ti e lasiko yi, Kolawole Adejojo Kasnaty ni Femi Omilani je, eyi lo si fe je kawon kan maa ro pe Kasnaty ko gba ti Omilani bo tile je pe okunrin naa ko tii soro jade.

Gbogbo igbese lati ba Ogbeni Kasnaty soro lori ibi to fi si, iyen eni to fe e tele laarin Omo Baba Tisa ati Omilani lokunrin naa ko so jade sita, se lo kan n so pe ibo loun tun un fe e wa bi ko se ibi tawon eeyan ro si na.

Nnkan to kan maa n ya eeyan lenu bi Kasnaty se maa n beru lati da si oro oselu to ba n lo kaakiri, nitori wahala ti ko fe e fa si ara lese, se lo n so pe oun mo n ba ara oun.

Nigba ti Kasnaty seto lojo Eti Fraide to koja, ibi tawon eeyan foju si nipa nnkan to fee so ni ona ko gba ibe rara, nigba taa si bi leere pe ki lo de ti ko soro lori nnkan to n lo ninu egbe won, se lo so pe oun ko loro lati so, sugbon oun to da wa loju ni pe aya e lo n ja.

Kasnaty ati Omilani
Iyalenu lo je lonii nigba ti Kasnaty kede lori eto e kan to maa n se nilleese redio molebi, Family FM to wa nilu Abeokuta laaro ojo Aje Monde pe oun fee soro lori egbe sorosoro FIBAN, to si so pe bo ba n sunmo akoko idibo, o lawon nnkan to maa n lo laarin awon adije.

Opo awon omo egbe to gbo eyi la gbo pe won bere sii pe ara won lori aago pe Kasnaty fee soro, o fee bo, oro fee jade, ki won tete si ero redio won sibi ti Kasnaty ti n seto lowo, ti gbogbo won si bere sii fori gbari lati sunmo redio won.

Eyi ko ya olootu iroyin AWIKONKO soto, nigba toun naa fi nnkan to n se sile lati teti gbo nnkan to fee so, sugbon nigba to di aago mewa ku iseju bii mejo, lokunrin naa so pe bi idibo ba ti n wole, o lawon igbese tawon to ba fe e dije maa n gbe, iyen ni pe won ni lati gba foomu.

Gbogbo eeyan lo mo eyi tele, sugbon iyalenu lo je nigba to je pe asiko ti won so pe foomu naa maa kogba wole ni Kasnaty kede sita pe oni (iyen lana Monde) gan gan ni foomu naa maa kogba wole, nitori naa kawon to ba fee gba foomu lati dije loo tete gba foomu won nitori pe egberun marun un naira tun maa gun ori owo foomu naa bo ba fi le di ojo keji.

Eyi lo je kawon kan so pe maanu ti won n pe ni Kasnaty yi, opolo ko je ko sun, won ni ko gbadun rara fun bo se da awon laamu yi, nitori pe nnkan ti won lero pe won fee gbo lenu e ko ni won gbo yen.

Se ni won lero pe o maa soro lori adije to fee tele laarin Omilani ati Omo Baba Tisa. Sugbon leyin bii wakati meta la sese gbo pe okunrin naa ti kede fawon omo egbe pe ki won teti leko lati gbo oun nipa oro egbe FIBAN toun fee so, ati pe o se pataki gan an ni.

Eyi lawon kan je ko ye AWIKONKO pe Kasnaty doju ti opo awon omo egbe naa latari bo se ge won lege, ti ko so nnkan ti won n reti pe ko so, sugbon ohun tawon kan so ni pe o dara bi okunrin naa se ran won leti pe ojo naa ni foomu yoo kogba wole, ti won yoo si fowo kun un.

Ju gbogbo e lo, se egberun marun un naira yi ko wa a poju fun owo tiwon fi kun owo foomu yi pelu bi eto oro aje orileede yi se ri lowolowo bayii to je pe agbara kaka lawon eeyan fi n se ipolowo lori redio ati telifisan? Ti won niyen sa.

E waa gbo o, bi Kasnaty ko ba tete soro sita yii, o seese ki AWIKONKO gbena woju okunrin naa nitori pe oun gan an lawon eeyan n reti lati soro, nitori bo ya yoo pada leyin eni to wa tele, Omo Baba Tisa ti yoo si tele Omilani to je omo leyin e tabi ko duro ti Omo Baba Tisa digbidigbi.

Oro m boroo bo, gege bi orin ti Alawiye n ko lenu ojo meta yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI