Asiri awon to pa oga oteeli Mafland n’Ifo ti tu o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 21, 2017

Asiri awon to pa oga oteeli Mafland n’Ifo ti tu o

Eni to ba foju kan awon afurasi odaran marun towo olopaa te loseLatigba ti Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu ti gbo pe awon odaran kan loo pa Oloogbe Oloye Moses Akanni Famuyiwa, eni odun metalelaadorin ti won loo ni Oteeli kan ti won poruko e ni MAFLAND nilu Ifo, ijoba ibile Ewekoro, lo ti pase pe oun fawon olopaa lojo kukuru lati mu awon afurasi naa wa siwaju oun ni Eleweran.

Awon odaran afurasi naa
Ni nnkan bi aago marun aaro, ojo kerinla osu yi, iyen Ojoru Wesde to koja lo lohun la gbo pe awon afurasi odaran naa, Dare Abiodun, eni odun mokandinlogun; Femi Ayinla, eni odun metadinlogun; Abduliamin Akinlotan, eni odun mejidinlogun; Jamiu Akeweje, eni odun mokandinlogun ati Gbenga Ojo toun je ogun odun ni won loo ka okunrin naa mo ile okan lara awon iyawo e lagbegbe Arigbajo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, awon mejo ni won so pe won loo ka okunrin naa mo, ti won si gun un nigo lowo osi e, ki won too gba baagi e to ko owo to to egberun lona oodunrun (N500,000) naira, ti won si salo.

Gbogbo awon ti won ni won ba ninu ile lojo naa ni won ni won se lese pelu awon eroja ti won ko dani, sugbon bi won se lo tan ni won sare gbe baba agbalagba naa lo si okan lara awon osibitu to sunmo fun itoju.

Oro yi pada nigba ti won ni okunrin naa ku ki won too de osibitu naa, tawon ebi naa si fi ibinu loo foro naa to Komisana olopaa leti lati tete bawon wa awon to seku pa olori ebi won.

Loju ese ni Iliyasu ti ranse si oga olopaa ekun Ewekoro, Ogbeni Vincent Egwuonu pe ko tete wa nkan se soro naa ko too di pe owo te awon afurasi marun yi.

Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n foro naa to AWIKONKO leti, o so pe awon afurasi marun towo te yi ti jewo pe looto lawon loo gba baagi owo to to egberun lona oodunrun naira naa, tawon si tun gun okunrin naa nigo, sugbon kii se ibi tie mi e ti le lo si lawon ti gun un.

O ni lesekese ti Iliyasu ti foju kan awon afurasi odaran naa lo ti tare won sodo eka olopaa to n ri soro awon odaran, iyen Criminal Investigation and Intelligence Deparment lati se iwadi to to ati eyi to ye, ki won si le ri awon odaran to ku naa mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI