Idanilekoo Ramadan ti fasiti Funaab; ojo malegbagbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 21, 2017

Idanilekoo Ramadan ti fasiti Funaab; ojo malegbagbe

Titi di bi a ti n koroyin yi lowo lawon eeyan si n royin idanilekoo aawe Ramadan ti agbarijo Musulumi, eka ti ileewe fasiti Federal University of Agriculture, FUNAAB nilu Abeokuta se lose to koja nibi ti awon ojogbon atawon oga agba nileewe naa ti peju se e.
 
Gege bi AWIKONKO se gbo, idanilekoo naa to je eleeketadinlogbon iru e ni won sori e ni Asigba ekoo awon Musulumi: Ohun to n faa ati ona abayo, iyen “Mis-education of Muslims: Issues and Way Out”, ti oludanilekoo ojo naa, Dokita Ahmad Yahya ti so awon isoro to n doju ko esin Islam paapaa lorileede yi.

Nibe ni Dokita Yahya ti so die ninu bi itan eko se wo orileede Naijiria lati mu olaju bawon araalu nipa esin. O lawon omowe ni won mu esin naa wa nipa dida ile Olorun sile, ti won si tipase e bere sii ko awon eeyan lawon nnkan ti won ko mo, ati bi won se n ko nkan sile.

Bee lo so pe ko seni to le ko eeyan lekoo lai je pe eni to fee ko naa mo si, o ni eko ko see fi sere, teeyan si gbodo muu lokunkundun. O wa gbawon eeyan lamoran pe ki won rii daju pe esin ati eko ti won gba naa je won logun.

Awon alejo
Saaju akoko yi ni Ojogbon Kehinde Okeleye ti gboriyin fawon alakoso ileewe naa, paapaa Adele Giwa, Ojogbon Ojogbon Enikuomehin fun anfaani to fi sile lati wa nibi eto idanilekoo naa.

AWIKONKO gbo pe owo to fee to aadota milionu (N46,000,296) naira ni won ti na lori kiko mosalasi ogba ileewe naa, eyi to je pe ida mejilelogorin owo naa lo je pe awon omo egbe Islam ileewe naa lo fi sile nipa owo osu won, ti eyi to ku si je eyi tawon alakoso ileewe naa fit a won lore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI