Baba agbalagba to fipa b’omodun mefa sun dero atimole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 15, 2017

Baba agbalagba to fipa b’omodun mefa sun dero atimole

Beeyan ba wa nibi ti won ti fesun kan baba agbaradarada kan, Isiaka Obadairo, eni odun mejilelaadota pe o fipa ja ibale omodun mefa kan taa foruko bo lasiri l’Ojoru Wesde, ojo kerinla to koja yi yoo mo pe ile aye pe meji.


Baba agba radarada naa re e
Gegebi AWIKONKO se gbo, ojule kejilelogoji, agbegbe Ijamido, layipo Osi nijoba ibile Ota (No 42 Ijamodo Estate, Osi Round about Ota) lowo olopaa ipinle te Isiaka leyin ti iya omo naa. Arabinrin Comfort Ajayi loo fejo sun awon olopaa.

Bawon kan se n so pe oro baba naa lowo aye ninu, kii soju lasan, bee lawon kan n so pe Isiaka mon on mo se ise buruku yi ni, nitori ti won so pe nnkan to n wa loju e ri.

Ohun taa gbo ni pe lakoko tiya omo naa, Comfort ti lo sibi to ti n sise ni  Isiaka ri aaye lati pe omo naa wole bii pe oun fe ran nise, to si se bee bo pata e, titi to fi gbe kini nla abe e somo naa nidi.

Inu ile kan naa la gbo pe Comfort ati baba agbaya yi jo n gbe e, to si maa n ran omo naa nise lasiko to ba wuu, yato si ale, lai mo pe okunrin naa n wona bi yoo se fipa ba omo naa sun ni koro.

AWIKONKO gbo pe gbogbo bi Isiaka n fipa ba omokekere yi lo po lomo naa n sunkun, sugbon ko raaye pariwo sita nigba ti won so pe se lo faso dii lenu, ki ohun ma baa ja geere sita gbangba.

Won ni bo se setan lo bee omo yi, to si ko eru si lokan pe to ba file so fun mama e, oun maa pa ni. Sugbon nigba ti Comfort maa de lati ibise, se lo ri eje to n da labe omo e, to si beere pe ki lo se.

Lesekese lomo naa jewo pe baba agba radarada Isiaka lo fipa ba oun sun, to si fa abe oun ya. Ko too soro tan ni Comfort pariwo sita pe kawon araadugbo gba oun lowo Isiaka nitori pe o ti ba aye oun je.

Bawon ti won jo n gbe se gbo oro naa ni gbogbo pariwo sita ti won si bere sii luu Isiaka ko too di pe Comfort gba tesan olopaa lo lati loo foro naa to won leti.

Bi oga olopaa ekun Ota, Ogbe Ogunwale Akinsola se gbo lo sare gbera lati loo mu Isiaka tori oun ti won so ni pe o seese ko na papa bora bi won ko ba tete debe, ti won si muu wa si tesan won nibi ti won ti foro waa lenu wo.

Nibe lo ti jewo pe looto ni ati pe ise esu ni. O loun ko mo nnkan to ti oun lo sodo naa. Isiaka ni boun se se kinni naa tan loju too la, toun si kawo lori pe ki loun se yii. O ni latigba toun ti see tan leri okan ti bere sii je oun pe asiri si maa tu, toun si n be omo naa pe ko daso asiri boun.

Lesekese ni won ti gbe omo ti Isiaka fipa ba sun yi lo si osibitu fun ayewo, ki won si se itoju e bo ti to ati bo ti ye, ki wahala ojo iwaju ma baa ba omo naa.

Nigba to n jeri soro naa, Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe looto loro naa, ati pe Isiaka ti wa ni oluleese olopaa to wa ni eleweran, Abeokuta nibi ti won ti n foro wa lenu wo.

Oyeyemi so pe lesekese ti Komisana awon, Ahmed Iliyasu ti gbo lo ti pase pe ki won tare Isiaka sodo eka olopaa to n ri si lilo omo nilokulu, ati fifi omo se owo eru lati tubo sewadi, to si seleri pe Isiaka ko ni pee foju bale ejo.

Iliyasu wa gbawon obi ati alagbato lamoran pe ki won ri daju pe won n bojuto awon omo won, paapaa ki won maa mo iru ise tabi awon ti won n fomo won ti, nitori pe awon eeyan buruku yi si po laarin ilu.

O tesiwaju pe ipinle Ogun ko ni gba oun atawon odaran nitori pe emi ati dukia ati alaafia awon eeyan ipinle naa lo je oun logun. Bee lo ro awon eeyan pe ki won ma se dekun lati maa foro awon odaran to ileese olopaa leti ki eto aabo tubo le kesejare.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI