Gongo fee so ni nileewe FCE Osiele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 14, 2017

Gongo fee so ni nileewe FCE Osiele

Iroyin to n lo kaakiri igboro paapaa nile Yoruba bayii ni ti ayeye olodoodun kan to maa n waye ni ileewe giga Federal College of Education, FCE Osiele to wa nilu Abeokuta, ipinle Ogun lojo keje osu keje to n bo yii.

Iwe ipe
Ayeye naa ko pe meji, ohun ni Ogo Oodu ti Egbe Osere Ogo Oduduwa, eka eko ede Yoruba maa n sagbateru e lodoodun lati fi gbe ogo Yoruba laruge, ti won si maa n fi anfaani e fawon eeyan jankan-jankan lawoodu.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ona ara-oto layeye todun yi fee gba waye nitori pe gbogbo eto lo ti to ni ti imurasile won.

Opo awon oba alaye nile Yoruba bii Olu-Itori, Oba Abdulfatai Akorede Akamo; Oba Oluwasesan Ogunmuyiwa, Elejio tilu Ejio; Oba AbdulRasak Adewusi, Oni Ijowun tilu Ijowun; Oba Ezekiel Alani, Olososun tilu Ososun atawon min in ni yoo wa nibe.

Nigba to n for naa to AWIKONKO leti, Aare egbe osere ogo Oduduwa, Ogbeni Sanni Arewa so pe awon osere bii Odunlade Adekola, Toyin Adegbola, Asewo to re Meka ati Sahee Osupa, Afeez Eniola, Kunle Afod yoo wa nikale lojo naa.

O si awon yoo fi aami eye awoodu dawon eeyan lola lojo naa, bee ni ere ori itage, ijo bata, ijo eyo ati ere sango lawon yoo safihan e fawon eeyan to ba wa lojo naa, gege bi eto tawon ti la kale.

Bee lo tesiwaju pe awon sorosoro bii Moruf Adegboyega, Omodo Agba ati Aare Abiodun Adeoye, Afefe Oro ni yoo dari eto naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI