Evans re o |
“Awa ko, Olorun ni” lorin tawon olopaa kaakiri
orileede yi mu bo enu lojo Abameta Satide to koja yi nibi ti won ti n sajoyo
latari ti ogbologbo olori awon ajinigbe lorileede Naijiria towo won ba.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, kii se ise odun kan tabi meji lawon olopaa se ki won too ri Chukwudidumeme
Onuamadike tawon eeyan mo si Evans, eni odun merindinlogoji. Opo wakati lawon
olopaa ati iko Evans fi koju ibon sira won ko too di pe owo palaba won segi.
“E fi oro mi kogbon,
gbogbo eyin ti e si n ji eeyan gbe. Inu mi baje pupo” loro ti Evans omo bibi
abule Umudim nijoba ibile Nnewi North nipinle Anambra, eni tawon omoleyin oga
olopaa, iyen Inspector-General of Police Response Team, IRT lo mu ninu yara e
nile to ko si Magodo ipinle Ekoo n so.
Evans lakoko iforowero |
Saajo akoko ti won ri
Evans mu lawon olopaa so pe awon yoo fun eni to ba bawon rii ni owo to to
milionu lona ogbon naira, gege bi owo gba mabinu, o kuu ise takun-takun.
Kii se ipinle Ekoo
nikan ni Evans ti je baba isale fawon ajinigbe, kaakiri orileede Naijiria. Opo
awon osise ni ogbologbo odaran yi ni to n baa sise. Lara awon ilu ti won ti n
sise ju ni Ekoo, Port-Harcourt, Onitsha, Aba ati beebeelo.
Lodun 2013 ni Evans
gbero lati ji eni to nileese moto Young Shall Grow.
No comments:
Post a Comment