Lojo ti Adele Giwa Funaab sabewo sawon akekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 14, 2017

Lojo ti Adele Giwa Funaab sabewo sawon akekoo

Idunnu subu lu ayo awon akekoo fasiti ogbin, Federal University of Agriculture to wa nilu Abeokuta, iyen awon akekoo to n gbe inu ogba naa lojo ti Adele Giwa ileeko naa, Ojogbon Ololade Enikuomehin sabewo si won, lati mo bi nkan se n lo si pelu won.

Lakoko abewo naa
Kii se pe Ojogbon Enikuomehin deede loo ki awon akekoo naa bi ko se pe lati mo awon ibi ti ise ku si lodo won, ati lati le dahun awon ibeere latari awon isoro ti won n koju nibi ti won n gbe naa.

Ariwo idunnu pe VC ti de lo gba enu gbogbo awon olugbe ogba naa lojo yi, ti won si bere sii korin “ise re maa n te wa lorun”.

Nigba tawon akekoo naa n soro ni won so pe isoro tawon n koju ko se e ka tan, nitori pe ojoojumo lawon n fi to awon alabojuto leti, sugbon ti won n foni-doni, fola-dola fawon lori e.

Lara awon isoro ti won ka sile lojo naa ni airi omi to to won lati lo, paapaa ti kii yo lojoojumo, awon ero awon sokeeti ti won n lo nile idana, awon ero amunawa to denu kole, faanu, ibi ti won ti n fo abo ati aso, ile igbe, aga ijokoo, beedi to denu kole.

Awon mi in ni aga ijokoo ninu yara ikawe, ero ti won fi n gbowo, iyen ATM, papa isere boolu alapere (basket ball) atwon min in.

Nigba to n soro lakoko abewo naa, Adele Giwa, Ojogbon Enikuomehin so pe o ye ki igbese wa lori ona ti won le gba pese awon ohun amayederun fawon akekoo to n gbenu ogba naa lore-koore.

Enikuomehin ro awon akekoo naa pe ki won si maaa farad a awon nkan ti won n koju, nitori pe fungba die ni, tori pe laipe lawon yoo wa iyanju si leyin tawon ba setan ninu iwadii won.

O ni ki won ma se dekun lati maa fi awon edun okan won to awon ti won yan sodo won leti, iyen Dean of Student Affairs ki won si maa fi to awon naa leti, lati le dekun awon isoro ti won ba n koju.

Ojogbon Ololade so pe oun ti setan lati gbin fi apeere rere lele nipa ooto, nigba to n gbawon akekoo naa lamoran pe ki won dojuko nnkan to gbe won denu ogba naa, ki laala awon obi won ma baa ja si asan, ati pe ki asiko tawon naa yoo lo ninu ogba naa ma baa lo lofo.

Nigba toun naa n soro, igbakeji Giwa nipa eko nileeko naa, Ojogbon Oluwayemisi Eromosele gbawon akekoo naa lamoran pe ki won ri daju pe won saboju to awon nnkan ti ileeko naa pese fun won, ki won si maa tun un se ni gbogbo igba ti won ba n loo tan.

Bee lo ran won leti pe ki won tete loo foruko sile nipa eko ti won fee ko, ki won si rii daju pe won san owo ileewe won lasiko ki asiko too lo.

Gege bi a se gbo, awon ibi ti Ojogbon Enikuomehin atawon alakoso ogba naa sabewo si ni gbongan ileegbe Iyalode Tinubu topo mo si IYAT; Gbongan ileegbe Umar Kabir; ileegbe awon obinrin ti won sese ko ladojuko osibitu ti won ti n ko eko nipa abojuto ohun osin, Veterinary Teaching Hospital ti won tun mo si Marble Lodge atawon min in layika e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI