FUNAAB yan adele regisiira tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 5, 2017

FUNAAB yan adele regisiira tuntun

Ile eko giga fasiti ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta ti kede Dokita Arabinrin Linda Onwuka gege bi adele regisira (Registrar) leka eko ona jinjin, iyen Distance Learning Programme nile eko naa.
 
Gege bi AWIKONKO se gbo, nibi ipade igbimo alakoso ile eko naa eleekerinlelaadorun iru e to waye laipe ninu ogba naa ni won ti yan Dokita Linda pe ki o bere ise ni pereu lojo kinni osu yi, iyen osu kefa.

Bi won se yan Dokita Linda ko seyin bi eni to wa nibe tele, Ogbeni Mathew Ayoola se gbe ipo naa sile  leyin odun marun gbako to ti n lo ipo naa bo. Ojo kinni osu kefa odun 2012 la gbo pe won yan Ogbeni Ayoola ti saa e si pari lojo mokanlelogbon osu karun.

Nigba to n dupe lowo ile eko naa atawon alabasisepo e, Ogbeni Ayoola so pe ko sohun to ni ibere ti ko lopin, o ni opo ni won maa n bere nkan boya nipa anfaani tabi won ye fun un sugbon ti won ko ni ni oore to to lati yori sibi to lapeere, sugbon toun ko ri bee nitori pe koko lara oun si le lati sise siwaju sii.

O wa ki eni to gbe ipo naa fun, Dokita Linda ku oriire, o ni ipo naa ko le sajeje sii nitori pe o ti wa nibe tele, o si ti mo bi nnkan se n lo.

Nigba toun naa n soro, Dokita Linda so pe looto loun ti wa nibe tele tawon nkankan si ti yi pada, sugbon awon ayipada naa ko le yato sawon nkan toun ti mo tele.

Saaju akoko yi ni Adele Giwa, Ojogbon Enikuomehin ti ki obinrin naa ku oriire fun ti ipo tuntun naa, nigba to n so pe ko gbiyanju lati se daadaa lakoko to maa lo nipo naa.

Gege bi AWIKONKO se gbo nipa Dokita Arabinrin Linda Onwuka, won lobinrin naa ti figbakan je asaaju leto oro epo robi nile eko naa ni Effurun, ipinle Delta fodun marun un.

O gba iwe eri Bachelor of Arts ati Ph.D nile eko fasiti Ibadan, o ni Masters Degrees nile eko fasiti Calabar, bee lo ni Postgraduate Diploma neto Eko, iyen PGDE. Opolopo aami eye, awoodu lobinrin naa ti gba, lara eyi to gba ni fasiti Ibadan, eka tilu Wari lodun 2011.

O je okan lara awon omo egbe Chartered instatituted of Personnel Management, CIPM; Nigeria Institute of Management, NIM; Association of the Nigerian University Professional Administrators, ANUPA; National Association of Teachers and Researchers in English as Second Language, NATRESL; National Oral LiteratureAssociation, NOLA ati English Language Teachers Association of Nigeria, ELTAN.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI