FUNAAB fee ko ileese olopaa agbegbe s’Alabata - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 5, 2017

FUNAAB fee ko ileese olopaa agbegbe s’Alabata

Idunnu subu lu ayo awon ara Alabata l’Ojobo Tosde to koja yi nigba ti ile eko giga fasiti ti ogbin, Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB, ajo PCRC ati ileese olopaa ipinle Ogun towo bo iwe adehun lati ko ago olopaa agbegbe (Community Police Station) silu naa ki eto aabo le tubo kesejare.
 
Won si ti wa fi ipile ile kiko ago olopaa naa lele bayi nigba tawon eeyan bi Adele Giwa ile eko naa, Ojogbon Ololade Enikuomehin, Ahmed Iliyasu, to je komisana olopaa atawon agbaagba nilu naa pejo lati sayeye.

Gege bi atejade ti olori alukoro ile eko naa, Arabinrin Emi’ Alawode fi sita, eyi ti eda e te AWIKONKO lowo se so, igbese yi waye latari bi won se so pe awon adigunjale, odaran atawon agbebon se n fojoojumo yo won lenu loorekoore, eyi ti won so pe ko fi okan awon eeyan, paapaa awon akekoo bale, to je pe inu iberubojo ni won ti n lo igbesi aye won nibe.

Nigba to n soro nibi ti ayeye ifilole ipile naa ti waye, iyen ni Harmony Estate to wa nitosi enu ona abawole fasiti naa, Adele Giwa, Ojogbon Enikuomehin so pe awon akekoo lo po ju to n gbe ilu naa, ati pe alaafia won lo si je oun logun ju.

Enikuomehin ni idagbasoke eto oro aje agbegbe naa ko seyin awon akekoo to po ju nibe, to si ye ki won daabobo emi ati dukia won. O ni bawon akekoo naa ko ba n gbe be, ko ni sidi kan ni pato tawon yoo fi so pe kawon gbe igbese naa.

O so pe awon gbodo roo sotun ati osi, ati pe tawon ba n wo wahala to n sele nibe, awon si tun gbodo wo ti igbe aye won peluu. O ni awon yoo se ohun to ba ye lati je ki won maa ri awon akekoo won pelu oju omo gidi lawujo.

Bee lo so pe bi won ba ri tawon akekoo naa n hu awon iwa ti ko bojumu, kaka ki won ba won fa wahala, ki won koko wa fi to awon alase leti lati gbe igbese lee lori nitori pe ofin ati ilana to de iwa awon akekoo wa nile tawon yoo fi gbe igbese.

Saaju akoko yi ni komisana olopaa, Ahmed Iliyasu so pe ko sigba toun gbo nipa olopaa agbegbe (community policing) ti inu oun kii dun, nitori pe awon ko le se aseyori lai je pe awon ni ibasepo to danmoran pelu awon araalu nitori pe awon gan an ni won le je kawon mo bo se n lo.

O so pe idunnu olopaa ni lati ni ajosepo pelu awon egbe, ajo atawon araalu lati le maa mo bi nkan se n lo si lagbegbe won, nitori pe alaafia, aabo emi ati dukia awon araalu lo je ileese olopaa logun julo.

Iliyasu tesiwaju pe oun ko le so bi inu oun se dun to bawon nkan meremere se n sele lasiko toun nipa idagbasoke eto aabo, o lawon yoo tubo maa fowosowopo pelu awon ajo, atawon eeyan laarin ilu lati le wa ni isokan, bee lo so pe awon ode naa wa lara awon tawon ni ajosepo pelu.

Alaga agbegbe Harmony, Ogbeni Emmanuel Abu to je osise feyinti ile eko naa nigba toun naa n soro so pe ko din ni ida aadorun ninu ogorun lawon akekoo fasiti FUNAAB to n gbe lagbegbe naa, awon si lawon gbemi le nipa eto oro aje to n wole sibe.

O wa lo akoko naa lati dupe lowo Giwa ana, Ojogbon Oyewole fun bo se fowo si owo milionu meedogun lati fi seranwo fun kiko ago olopaa naa. Bee lo dupo lowo Ojogbon Kola Adebayo to je alokoso Grant Management nile eko naa fun ti ile pulooti merin ti won n ko o si.

Bakan naa ni alaga ajo to ri si ajosepo laarin olopaa atawon araalu, iyen Police Community Relation’s Committee, PCRC, eka ti Obantoko, Onarebu Taiwo Akinlabi gbawon eeyan lamoran pe ki won fowosowopo lati da si eto aabo laarin ilu nipa ti ta awon olopaa lolobo awon odaran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI