Okan lara awon agba
osere tiata, eni to ti figba kan je Gomina egbe osere ANTP nipinle Ogun, Alaaji
Lateef Lolade Deinde ti so pe ko si nkan to n sele ninu egbe osere tiata bi ko
se pe asiko onikaluku lo ju.
Alaaji Deinde soro
yi latari awuyewuye to n lo kaakiri ilu nipa iku awon osere meta to tele ra won
leekan naa, o ni sababi lasan ni bi iku won se tele ara won je, kii se pe nkan
miran n sele.
O so ninu oro e pe “Irinajo
eda laye yi dabi keeyan wo oko lati Osodi si Sango ni, bi oni kaluku ba de
ibudoko e, dandan ni ko bo sile, ko si nkan to n sele ninu egbe osere.”
O tesiwaju pe looto lo
je pe onikaluku lo ni anfaani lati so nkan to ba wu lenu, nitori pe iwofa lenu,
oun lo fa a tawon eeyan fi n so nkan toju won ri ati eyi ti oju won ko ri.
No comments:
Post a Comment