Ojo mejo gbako la fee fi ti ona Olorunsogo Abeokuta o – TRACE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 3, 2017

Ojo mejo gbako la fee fi ti ona Olorunsogo Abeokuta o – TRACE

Ajo to n ri si ilo geere oko loju popona nipinle Ogun, iyen Traffic Compliance and Enforcement Corps, TRACE ti so pe ojo mewaa gbako lawon yoo fi ti opopona Iyana-Motuari si Olorunsogo latari ti atunse to n lo lowo.

Ikede yi jeyo nirole ana Tosde nigba ti alukoro ajo naa, Ogbeni Babatunde Akinbiyi fi to awon oniroyin leti lati je kawon araalu mo bo se n lo ko too pe ju lati le mo bi won a se rin lawon ojo yi.

Akinbiyi so pe oni ojo Eti Fraide, tii se ojo keji si ojo Eti Fraide to m bo, iyen ojo kesan an osu yi laarin aago meje aabo aaro si mefa irole lawon yoo fi ti opopona naa lati le mu ki ise awon to n se ona naa le lo lai si idiwo fun won.

O so pe o ye kawon oko maa gba kan ni, sugbon awon ko nii fe lodi si ofin irinna pe ki moto meji koju sira won, iyen ti oloyinbo n pe ni One-Way lati le din ijamba oko ku loju ona naa.

O waa fi kun oro e pe awon ti seto bi awon oko yoo se maa rin nirorun, ni to n so pe awon oko to ba n bo lati ona NNPC, ki won gba adugbo Sam Ewang jade si Tekobo, Idi Aba, Elite lo si Moore junction.

Awon to ba n bo lati ona OGTV, Kemta, FMC, ki won gba adugbo Elite, SalamuKaola jade si Olorunsogo, Moore Junction. Bee lo so pe awon to ba n bo lati Isabo, Sapon, ki won gba Oja Ale jade si Isale Ake.

O wa so pe awon ti seto awon osise awon lati maa dari awon oko sibi to ye ki won gba, fun irorun awon awako kaakiri Abeokuta.
aa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI