Matthew sa baba to gbaa sile nibi to ti lo jale pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 20, 2017

Matthew sa baba to gbaa sile nibi to ti lo jale pa

Ewon loun atawon egbon e wa bayii

Oloogbe losibitu
Beeyan ba wa nibi ti iya arugbo kan, Kehinde Odeyemi ti n gbera sanle lojo Abameta Satide to koja yi nigba to gbo pe oko e ti dagbere faye latari bi won se so pe won sa lada lori.Adugbo kan ti won n pe ni Abatabutu, Odugbe nijoba ibile Ado-Odo Otan nipinle Ogun ni won so pe Odomokunrin tojo ori e ko tii ju ogun odun lo, Matthew Elegbede fe loo jale lojo Aiku Sande to lo lohun ni nnkan bi aago mewa ku iseju mewa, ti asiri e si tu sawon araale to fee ja lole naa lowo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni nibi ti Matthew ti n yo gilaasi ojo findo, iyen louvers ni won so pe o ti jabo lu obinrin to ni yara to fee gba wole lori beedi, tiyen si taji, to fi pariwo ole.

Won ni se ni Matthew duro gbogbo bi won se n pariwo ole, ko salo tawon araale naa fi jade sita, ti won si muu mole. Asiko naa ni won ranse pe baba to nile naa, iyen Oloogbe Ogbeni Albert Adebari Odeyemi, eni ti won so pe oju oorun lo wa ti won fi loo pe.

Nigba to n ba AWIKONKO soro lojo abameta Satide to koja yi, obinrin to ni yara naa, Arabinrin Victoria Omiata so pe oju oorun loun wa ti gilaasi fi jabo lu oun lori beedi toun sun si, o laya oun ja loun fi sare dide bo sita toun si bere sii pariwo ole.

Lesekese lo so pe awon araale ti jade lati loo wo eni naa, sugbon iyalenu lo je pe omo naa ko salo, ti won si mu sita, o ni ariwo tawon n pa lo je kawon araadugbo waa wo nkan to n sele, ti won si so pe omo adugbo ni.

Victoria
Victoria so pe Baba onile awon, iyen Oloogbe Odeyemi loo so pe ki won fi sile, ti ile ba mo, awon yoo loo foro e to awon eeyan e leti lati wa nkan se si, o nibi tawon ti n soro naa lo ti dogbon kuro laarin won, laimo pe o nise ibi kan to fee se.

O so siwaju pe ko ju iseju marun to kuro laarin awon lawon gbo ariwo moto tirela nla, to n sare wa bo, to si waa di oju titi niwaju ita pe ko si moto to maa koja, bo se sare bo sile niyen to si n fi ada le awon kaakiri.

Obinrin naa so pe Oloogbe Odeyemi nikan lo duro pe kawon gba ada naa lowo nitori pe se loo tun loo pe awon egbon e meta kan wa lati wa fa wahala naa, ti won si bere sii lu awon eeyan nilukulu.

O loun ni Matthew koko fi ada naa le wonu igbo to je pe Olorun lo yo oun, leyin to pe die loun gbo pe o fi fada naa sa Baba Odeyemi lori, ti won si ti gbee lo si osibitu kan to wa ladugbo fun itoju.

Alaroye gbo pe, se ni Matthew loo pe awon egbon e, Funmi ati Sunday to n gbe lodo won pe awon kan fi gilaasi sa oun lowo, won si tun lu oun, lo je kawon yen naa dide lati waa gbesan, lai beere boro naa se je ko too di pe won bere sii fada le awon eeyan kaakiri.

Akanji Fatolu
Okan lara awon to sunmo oloogbe naa, eni to tun je alaga egbe awon ajorin (welder) ti egbon Matthew, Sunday je igbakeji e, Ogbeni Akanji Fatolu nigba toun naa n soro lori isele naa, so pe ibi toun fegbe lele si ni oloogbe Odeyemi ti waa pe oun pe won mu ole nile keji e, kawon jo lo.

O so pe bi omo ni baba naa se mu oun, to si je pe ko si ojumo kan ki baba naa ma de soobu oun, nitori oun nikan ni oludamoran toun le so pe oun ni. O ni odo oun ni baba naa wa di nnkan bii aago meje aabo ale ojo naa, sadede loun tun ri won ni nnkan bii aago mokanla n loolu.

Akanji so pe idi ti won fi waa ba oun ni pe, won ni won ti wa awon ebi Matthew lo sile, sugbon won ko ba won, won lawon n wa nomba ti won le pe egbon Matthew, iyen Sunday si tori awon jo n se egbe kan naa ni lo je ki won wa boya oun le fun won.

O lawon tun pada wa won lo sile tawon ko si ba won, kawon too tun pada, o loju titi niwaju ita tawon wa lawon ti ri tirela to n sare bo, o so pe kani awon ko tete sa segbe ni, ko ba fi tirela naa kolu awon, ati pe se loo fi tirela naa di oju titi pe moto kankan ko nii koja.

O ni kani oun mo pe oro naa maa le to yen ni, oun ki ba ti duro, sugbon se loun kuro nibe, o ni ko tii ju ogun iseju toun pada dele ni won tun wa pe oun pe won ti sa baba lada lori, toun si pe Sunday lati beere nkan to sele lowo, sugbon nkan to so ni pe won ti sa aburo oun naa lowo.

Oloogbe nigba aye e
Akanji ni gbogbo boun se n ba soro lori aago ko fee soro, lo je koun dide loo bawon, sugbon iyalenu lo nigba toun de be, toun si ri bi won se sa baba naa lada lori, ko too di pe awon sare gbe won lo si osibitu kan to wa nitosi.

O ni leyin tawon kuro nibe lawon eeyan baba loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si so pe won bo tile ba ti mo. O so pe nigba tile mo toun so fun Sunday pe won sa baba gan an lo n beere lowo oun pe talo sa.

O laaro kutu lawon olopaa Atan ti wa ko won, sugbon nigba ti won ri pe oro naa koja agbara won lo je ki won ko won lo si tesan Ilaro nibi ti won ti fesun kan won.

Ohun taa gbo ni pe Sunday, Funmi ati Matthew lawon olopaa ko, ti won si foju won bale ejo lojoru wesde to koja, sugbon se ni adajo naa sun igbejo miran si ojo Aje Monde ana, lai mo pe baba naa maa ku.

Abiodun
Nigba toun n soro, okan lara awon baba, Abiodun Odeyemi to so pe Ore nilu Ondo loun wa nigba ti won pe oun ni nnkan bii aago mejila pe won ti sa baba oun lada lori, ti won si tun salaye oro naa foun, toun si seleri pe oun yoo yoju.

Abiodun so pe nigba toun maa de lojoru Wesde to koja, osibu jenera to wa ni Victoria Island nilu Ekoo ti won gbe baba oun lo loun ti loo pade won, o nibe ni won ti so pe kawon loo ya sikani ori baba oun.

O ni se lawon sare loo wa owo, iyen egberun lona ogbon naira tawon fi ya kinni naa, nibe ni won ti je kawon mo pe eje tit a si baba lopolo, to si nilo ki won sise abe fun won.

O loro bawon se maa sare wa owo lati sise abe naa lawon so lojobo Tosde mojumo Fraide, ko too di pe baba gbemi mi, o loju ese loun tun ti so fawon aburo oun pe ki won loo so fawon olopaa pe baba ti ku, ki won le mo bi won tun se maa gbe oro naa.

Abiodun so pe awon ti seto lati sin baba sugbon awon olopaa so pe awon ko tii gbodo sin in nitori awon gbodo sayewo kan ti won pe ni autopsy lati mo boya ada ti won fi baba lo seku pa won looto.

Kehinde, Iyawo oloogbe
Okunrin yi ti e je ka mo pe ipalemo ayeye ojo ibi ni baba n se lowo, to ri o ni baba pe oun losu to koja pe ojo kokandinlogbon osu gan an ni baba naa maa pe odun metalelaadorin, 73years.

Iyawo baba naa, Arabinrin Kehinde Odeyemi nigba toun naa n fomije b’Alaroye soro so pe baba sese jeun tan, o si ti sun ko too di pe won ranse wa pe awon pe won mu ole nile keji, tawon si gbera lati lo.

O ni aso inura, toweeli lo wa nidi baba to fi loo bawon. O so pe igba ti won bere sii fi ada le won loun sa wa sile, sugbon iyalenu lo je nigba ti won so foun pe won ti sa baba lada lori.

Ni bayii, ohun taa gbo ni pe awon olopaa ti yi ejo ti won fi gbe Matthew, Sunday egbon e, ati Funmi lo sile ejo pada si esun apaayan nitori bi won se so pe ori isele naa ni baba ku si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI