Mo ti di atunbi bayii – Toyin Aimakhu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 5, 2017

Mo ti di atunbi bayii – Toyin Aimakhu

Ilumooka osere tiata to maa n lo gbogbo ara e sinu fiimu bi eni pe ko sona atije miran fun un mo, Toyin Aimakhu ti so pe oun ti di atunbi kuro ninu iwa buruku to fee gbemi oun tele.

Toyin Aimakhu
Toyin soro yi lakoko to n dahun ibeere nileese telifisan kan laipe yi fun ti fiimu Alakada Reloaded to sese gbe jade latari awon ipenija to ti ba pade nigbesi aye e, ti ko le e gbagbe titi lai.

O so pe die lo ku koun gbemi ara oun nigba toro aye oun dojuru patapata, ti ko si salabaro foun toun le foro lo. O ni ironu wahala to ba oun yi lo so oun di amugbo, toun ko le se koun ma mu oogun oloro kokeeni lojumo.

Toyin so pe boun se n fa taba, bee loun n mu kokeeni bi eni mu omi, nitori iku loun n wa kiri nigba naa tori pe oun ko nironu meji ju boun yoo se gbemi ara oun latari oro aye oun to dojuru.

O lojoojumo loun sun ekun adasun bo tile je pe opo awon to n ri oun nigba naa lo n beere pe ki lo se oun, bo tile je pe ko seni to duro lati ran oun lowo, tori pe tonikaluku lo wa lara e.

O ni isoro yi lo gbe oun pade Seun Egbegbe to si je pe se lo n doju ti oun kaakiri. O ni kani oun fara bale pelu oko oun tele nigba naa ni, ati pe bi ironu oun se ri nigba naa ko faaye sile foun lati ronu daadaa rara.

Sugbon ni bayii, obinrin naa dupe gidi lowo Olorun to ra emi oun pada nitori pe igbe aye toun n gbe niisinyi ti yato si ti tele, oun ko si le mu awon nnkan buruku toun n mu tele mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI