Ko tii seni to le so ibi ti oro naa maa jasi laarin awon gbajumo osere
tiata nni, Saidi Balogun topo mo si James Bond ati Liz Anjorin ti won n pe ni
Aishat latari aawo to wa laarin won.
Saidi ati Liz |
Kii se ojo yen nikan lo da wahala sile bi ko se pe gbogbo awon ti Liz
ti kowe ranse si lati wa mu ojo naa dun ni Saidi Balogun naa tun pe fun ayeye
aadota odun e to fee se.
Eyi lo bi liz ninu ti ko si mo bo se fe e foro naa pamo sikun e, to si
je ko pariwo sita pe kawon eeyan gba oun lowo Saidi Balogo to fee ba toun je, o
lokunrin naa ko fe ilosiwaju rere foun lo se fe e di oun lowo.
AWIKONKO gbo pe lara awon ti Liz pe ni Gbenga Adeyinka ati Denrele Edun,
to si je pe fiimu ti liz fee se ifilole e yi, Saidi Balogun naa wa ninu e, to
si ko ipa to joju ninu e.
Nigba tobinrin naa n ba okan lara awon akoroyin Akede Agbaye soro lojo Eti Fraide to koja yi, o so pe se lo da bi
eni pe Saidi ko fe rere foun ni, nitori pe inu osu karun un loun ti koko mu
tele, sugbon ti Saidi naa so pe igba naa loun fee se ayeye aadota odun toun, ko
too di pe oun tun mu ojo keje osu keje.
O so pe iyalenu lo je nigba toun gbo pe ojo naa ni Saidi tun mu lati se
ayeye aadota odun e, to si je pe gbogbo awon toun pe sojo naa ni Saidi naa tun
pe fun ti pati too loun fe e se.
Liz so pe ohun yoo ba Saidi naa tan bi owo, toun yoo si lo agbara ati
ipo oun lawujo lati ba Saidi fa a debi to ba fe. O loun ko nii gba, a fi ki
Saidi ye ojo foun.
No comments:
Post a Comment