Nitori oyun; Funke Akindele soko oro sawon ololufe e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 27, 2017

Nitori oyun; Funke Akindele soko oro sawon ololufe e

Bee lo tun rawo ebe sawon ololufee nitori ayederu fiimu Jenifa’s Diary e

Funke
Gbajumo osere tiata obinrin nni, Funke Akindele topo mo si Jenifa ati Sulia kan ti soko oro buruku sawon ololufe e pe ki ni won fe e gbo lori oro oyun ti won loun ni.

Bo tile je pe asa Yoruba ko faaye gba pe ki oloyun maa gbe iroyin oyun e kaakiri ori afefe nitori ti won gba pe eewo nla ni to si le sakoba fun un yala lojo ikunle tabi ki oyun naa ma dale.

Iroyin tawon eeyan n gbe kaakiri ni pe Funke Akindele ti loyun, sugbon ti oyun naa ti jabo, eyi to fa ti won ni ko je ki obinrin aderin posonu yi ni anfaani lati maa yoju sita.

Bawon eeyan se n pariwo kaakiri, ti won n so orisirisi aheso nipa nnkan ti oju won ko too, tawon kan tun so pe obinrin yi n reti ibeji gege bi ayewo ti won loo se ti oko e naa si gbe sori ero alatagba.

Sugbon nigba ti okan lara awon ooniroyin kan sunmo Funke nibi apejo kan to waye ni gbongan Oteeli Eko (Eko Hotel), lo ti beere pe ki loo fe so nipa iroyin to n lo kaakiri igboro nipa oro oyun, sugbon nnkan ti Funke fi daa lohun ya ni lenu pupo.

Funke ni “Ki le fe ki n so, ki le fee gbo nipa e, sebi omo Yoruba niyin?”, lo ba rin kuro niwaju e.

Sugbon okan lara awon molebi Funke to sunmo on daadaa so pe inu Funke ko dun sawon iroyin to n gbo nigboro nipa e rara, ti won tun so pe oyun jabo lara e. Eni naa so pe Funke ko tii loyun rara. O kan wuu ko panumo fungba die ni, ati pe nile Yoruba, eewo ni kobinrin maa pariwo kaakiri pe oun ti loyun.

Lose to koja yi ni Funke Akindele lo anfaani eka ayelujara kan ti won n pe ni Instagram lati fi rawo ebe sawon ololufe e latari igbese to fee gbe lati koju awon to loo se ayederu fiimu atigbadegba e, Jenifa’s Diary ti won gbe sori ayelujara fawon eeyan lati maa wo lofe.

Nibi to ti so pe awon alase kan ti da soro naa, ti won si ti  bawon yanju oro awon to sayederu fiimu naa sita, ti won yoo si mu won bale lati fi won jofin.

Bakan naa ni oko Funke Akindele, to tun je gbajugbaja olorin taka sufe, eni topo mo si JJC Skillz gbe iroyin naa sori eka ayelujara Instgram pe loooto ni won ti bawon yanju e.

JJC tun fidi e mule pe Funke Akindele ti loyun, ko da, ibeji ni oyun to ni naa, ti Olorun yoo si je ko bii layo. Gege bo se fi idunnu naa han, okunrin naa so pe ko ni pe ti Funke yoo fi bimo naa.

Saaju akoko yi lawon kan ti n foro buruku ranse si Funke nitori ti ko yoju sibi ayeye isinku ti won se fun Oloogbe Moji Olaiya. Bo tile je pe won ti bere sii sakiyesi e Funke lojo Isegun Tusde ti won se eto ale awon osere, artistes night lati fi pon oku naa le, ti won si ro pe ojo keji ti won yoo sin, o gbodo yoju sibe.

Sibe won ni Funke ko yoju rara, nigba ti okan lara awon akoroyin si pe e lati bere idi ti ko fi yoju sibi eto isinku naa, se lo pa foonu e titi tile ojo naa fi su, ti ko so nkan kan di akoko yi.

AWIKONKO gbo pe ironu oyun ti ko tii ni lo fa ti obinrin yi fi fori e pamo sile, ti won si powe pe kini idunnu elewon to n pe omo alakara. Sugbon ni bayii, Olorun ti gbakoso, obinrin naa ti pada sita, to si ti n se awon nkan to ti pati tipe pada.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI