COLMAS FUNAAB; Awon ojogbon rawo ebe sijoba apapo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 22, 2017

COLMAS FUNAAB; Awon ojogbon rawo ebe sijoba apapo

Latigba ti Minisita foro eko lorileede yi, Ojogbon Adamu Adamu ti pase pe ki awon fasiti to doju ko ila eko kan tesiwaju ninu ilana eko ti won yan laayo, ki won yo awon ilana eko ti won ko mo won mo sugbon ti won n sise lori e kuro. Eyi ta ba opo awon fasiti bii FUNAAB; Poli atawon ile eko giga miran lorileede yi, to si fee fa owo aago won seyin.

Enikuomehin
Ojogbon Ololade Enikuomehin to je Adele Giwa ti wa so pe ki ijoba apapo se agbeyewo lori ipinu naa nitori eka ikekoo College of Management Sciences, COLMAS ti won fagile nileewe naa yoo se opolopo akoba fawon araalu, paapaa awon akekoo to ti fee setan.

Enikuomehin so pe awon akekoo to n jade lati eka ikekoo naa ko see fowo ro ti seyin larin awon akekoo jade lorileede Naijiria, nitori pe ona ti won gba lati ko won yato gedengbe sawon ileewe giga toku.

Enikuomehin ni imo nipa agbekale tawon fid a eka ikekoo naa sile lo n je kawon akekoo to wa nibe tayo koja oju tawon eeyan fi n woo. O ni eka ikekoo naa ko nii se pelu ise ogbin rara bi ko se pe won n ko won lona bi won se le se abojuto ileese atawon nkan amusagbara.

O tesiwaju pe yato si pe ajo JAMB kii fi eka ikekoo naa sita lakoko tawon akekoo jade ileewe girama ba fee se idanwo JAMB, sibe, awon ti won n foruko sile fun eka ikekoo naa po jaburata.

Saaju akoko yi ni Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo ti fi leta ranse sijoba apapo, nibi to ti fi eda e ranse si Aare orileede yi, Ogagun Muhammadu Buhari; igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo; Aare ile igbomi asofin agba, Dokita Bukola Saraki; Onarebu Dogara; Senato Lanre Tejuoso; Senato Buruji Kashamu; Senato Gbolahan Dada; Onarebu Segun Williams; Onarebu Mukaila Kazeem ati Ojogbon Abubakar Raheed to je akowe igbimo to n ri si oro ile eko fasiti lorileede.

Ninu leta naa ni Alake ti so pe ki ijoba apapo orileede Naijiria boju aanu wo ileeko naa latari eka ikekoo ti won gbegile, iyen COLMAS atawon akekoo to ti wa lenu eko naa ko too gbe ase naa jade, nitori pe ko sibi ti won fee lo, atipe saa awon akekoo kan ti fee pari, to si je pe se lawon akekoo kan sese wole, ko too dipe won gbe ase naa jade.

O so pe opo awon eleto eko, obi, alagbato, osise, akekoo atawon toro naa kan nipinle Ogun ati agbegbe e lo ti fehonu han, ti won si ti wa n ba oun lati wa nnkan se soro naa, eyi to si se oun laanu wipe oro naa n fe abojuto daadaa, atipe ki won yi ase naa pada.

Yato si Oba Gbadebo to bu enu ate lu igbese ijoba apapo yi, awon otokulu atawon eeyan jankan-jankan lawujo naa foro ebe ranse sijoba apapo pe ki won tete tun agbeyewo naa yewo nitori pe opo awon akekoo atawon obi ni won ti n kanminu lori ipinu naa.

Okan lara awon obi awon akekoo naa, to ti wa nipele keta, 300level, ko too di pe won fagile eka ikekoo naa, Ogbeni Olumuyiwa Adebari kanminu pe kijoba apapo tete bawon wa ona abayo sii nitori pe nibo ni won fe kawon ti bere latari egberun lona egberun naira tawon tin a lori awon omo won.

Okunrin naa nigba to n fehunu han so pe o ye ki ijoba so ona min in ti won fee gba lati ran awon eeyan lowo latari ipinu tuntun yi, ati pe ki ni yoo je ireti awon akekoo to ti wa ni ipele keta, to je pe o ku odun kan ki won setan gege bi akekoo gboye.

O ni awon alase kan ji lojo kan, won si gbe ipinu won jade lai ro ti akoba fawon araalu to le teyin ipinu won yo. O so pe won ko beere, won ko foro lo awon ojogbon to mo nipa eto eko lati gba amoran.

Bee lo wa gbawon akekoo toro kan lamoran pe ki won ma foya, ki won ma si je ki ipinu ijoba apapo ko irewesi okan bawon nitori pe igbese lati se atunyewo naa ti n lowo.

Arabinrin Iyabo Oloruntola nigba toun naa n soro so pe nibo nijoba apapo ti fe kawon akekoo bere bo se je pe awon to ku die ko kekoo gboye naa pelu awon toro naa kan.

Bakan naa ni okan lara awon akekoo eka ikekoo COLMAS naa, Afolabi Lukmon, eni to je agbenuso fawon akekoo Students’ Representative Council ti Students’ Union Government, SUG so pe edun okan ni igbese ijoba apapo naa n je fawon akekoo kaakiri lorileede yi, paapaa ou tou je pe odun to n bo loun maa setan.

O ni anfaani nipinu ijoba apapo yi maa je fawon orileede bii Togo, Benin Republic, Ghana atawon min in nitori pe opo awon akekoo lo maa fe lo sibe lati loo tesiwaju ninu eko won, eyi ti yoo si tun fi kun eto oro aje won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI