Odaran leni to ba san owo beeli lago olopaa – Oyeyemi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 14, 2017

Odaran leni to ba san owo beeli lago olopaa – Oyeyemi

Looto lopo awon araalu gba pe ofe ko ni beeli beeyan ba de ago olopaa, bo tile je pe ojoojumo lawon oga olopaa kaakiri orileede yi si n so pe ofe ni beeli. Agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n ba AWIKONKO soro nibi iforowero laipe yi ni ofiisi e to wa ni Eleweran Abeokuta, o tenumo on pe looto ni beeli je ofe. O ti e so pe odaran leni to ba sanwo beeli lago olopaa. Yato si eyi, Oyeyemi soro nipa bo se bere ise olopaa atawon nkan min in to sokunkun nipa eto aabo. E ka bi iforowero naa se lo.

Abimbola Oyeyemi
AWIKONKO: A mu ikinni wa fun un yin lati IROYIN AWIKONKO, nje a le mo yin lekunrere?
OYEYEMI: AbdulMojid Abimbola Oyeyemi loruko mi ti iya ati baba mi so mi lojo ti won bi mi.

AWIKONKO: Bawo le se bere igbesi aye yin ko too di pe e di alukoro fun ileese olopaa?
OYEYEMI: Omo bibi Iragbiji Olokemeji nipinle Osun ni mi. Mo lo si ileeko alakobere Methodist to wa ni Iragbiji, ki n to o tesiwaju ni ileewe girama Baptist to wa ni Iragbiji naa. Mo gbe ile daadaa ki n too kuro, mi o si le so ile nu. Leyin yen, mo lo si Yunifasiti Ilorin ti mo si pari ni odun 1995. Odun 1999 ni mo darapo mo ise olopaa. Ko pe ti mo darapo mo ileese olopaa ni mo lo si ileewe olopaa, Police College, leyin ti mo pari ni mo lo si ipinle Eko. Ipinle Eko yi ni mo wa titi di odun 20011. Odun yen ni oga olopaa lorileede yi nigba yen, Afiz Ringin lo ran gbogbo awa ti a niwe eri nla, iyen Degree pe ki won ran wa lo kekoo sii. Idi ni yi ti won fi fun wa ni igbega, ti won fun wa ni okun ASP (Assitant Suprintended of Police). Igba ti a pari leyin odun kan, won gbe mi wa sipinle Ogun, ti won si fi mi se igbakeji alukoro olopaa nigba yen, Omoba Muyiwa Adejobi. Nigba to di odun 2016 ti igbega de fun alukoro olopaa yi, iyen Adejobi ti won gbe e lo si eka keji ileese olopaa ti a mo si Zone 2 nipinle Eko, igba yen ni Komisana wa, Ahmed Iliyasu so mi di alukoro olopaa nipinle Ogun. Latigba naa la si ti n sise alukoro titi di asiko yii.

AWIKONKO: Lopolopo igba lawon maa n so pe awon ko le gba ki omo awon sise olopaa latari awon idi kan, ki lo faa to fi je pe ise olopaa yi gan an le yan laayo?
OYEYEMI: Beeni, paapaa julo nile Yoruba wa nibi, a kii fe nkan to ba le ju ogede lo. Ko po ninu awon omo Yoruba to je pe ojuboro, kii se agidi lo fi darapo mo ise olopaa. Emi naa nig ba ti mo darapo, mo mo nkan toju mi ri, ariwo ki lo n wa lo lo kun eti mi nigba naa lohun, sugbon nkan to ba wu ni lokan leeyan maa se. kii se pe airi ise lo mu mi wo ise olopaa, mo kuro nibi ise kan lati darapo mo ise olopaa ni. Opo awon eeyan lo si ya lenu pe ki lo de ti mo fi iru ise gidi bayii sile, to je pe ise olopaa ni mo wa a lo darapo mo. Mo nife si ise yi lo je ki n darapo mon on. Latigba ti mo ti wa nileewe alakobere ni mo ti feran awon ise to je pe ki a wo aso egbejoda, iyen Uniform. Mo n se Boyscout, Man-O-War pelu awon ise kan to nii se pelu eto aabo. Kekere nise olopaa ti wa lokan mi.

AWIKONKO: Oju wo lawon obi yin fi wo nigba naa, ati pe iha wo ni won ko sii?
OYEYEMI: Eeeh, se e mo pe ti won ba pariwo titi, sugbon ti won ri pe eniyen ko woo do won, nkan to ku ni pe kin bere sii gbadura pe ki Olorun se e ni ona e, tipatipa ni (Esu) fi n feran (Sango).

AWIKONKO: Bawo wa ni irn ajo yin gege bi ise olopaa?
OYEYEMI: Ko si ise ti ko si oke isoro kan tabi ikeji nibe, sugbon ti eeyan ba ti le duro, to si ni afojusun, eeyan a kesejare nibe. Lakoko naa, opolopo lo n so pe iwo ti o keko gboye, to n sise gidi, ki lo wa de to je pe ise olopaa ni mo tun un lo darapo mo gege bi contable, ki ni mo ro debe, sugbon Yoruba ni ti a o ba ku, a maa je eran to to erin. Ara ise to daa pupo nise olopaa, iyen bi awon eeyan wa ba se n se gege bo se ye ki won se e. irin ajo mi gege bi ise olopaa, igba lo le die wa nibe, awon asiko to si tun derun naa wa nibe, ni ile aye se wa niyen.

AWIKONKO: E o menuba boya e ko e ko eko nipa ede Yoruba, gege bi awon oro to n jade lenu yin?
OYEYEMI: Bi e ba woo, gege bi mo se so fun un, mo pe nile daadaa, mo si sunmo awon agba tori pe awon agbalagba lo to mi dagba. Awon ti ma sa baa maa n ba sore, awon to to mii bi lomo ni. Odo won ni mo ti n gbo orisirisi oro kanka ko too ba mi lara mu. Nkan ti a n gbo lenu awon agbalagba lawa naa fi n soro.

AWIKONKO: Nje e nigbagbo gege bi eto aabo pe e n daabobo ara yin, bii pe e n di ara yin lamure tabi nnkan min in?
OYEYEMI: Olorun nikan ni olori alaabo. Bi eeyan soogun titi, ewe a sunko lojo kan, sugbon ise Olorun nikan ni kii sunko. Adura nikan ni ko ni ojo taa fun pe ko sise da ti oloyinbo n pe ni Expiry Date. Ko da oogun oyinbo gan an ni ojo to maa fi sise da, sugbon titi lai ni adura. Ati pe se e mo pe awon to n sise buruku, emi to wa pelu ise ti won n se yen, ni yoo maa fi won le awa olopaa lowo, nitori pe okunkun ko le bori imole mole, eni to wa ninu imole gbodo bori eni to wa ninu okunkun. Ko digba teeyan ba n so onde mora, tabi to n gbe ijapa korun, Olorun nikan lo le daabo bo eeyan tori pe Oun nikan ni olori alaabo.

Oyeyemi
AWIKONKO: Ki ni awon adojuko yin ki e too depo tee wa yi?
OYEYEMI: Adojuko ko pe meji, bi ko se adojuko to wa fun gbogbo olopaa kaakiri. E mo pe ko si bi elede yoo se maa jejo ti esun oorun ko nii si nibe. Bi olopaa ba se n kan to da fenikan, eni yen yoo maa yin olopaa yen, sugbon enikeji to lo fi ejo sun, ti olopaa rii pe ko sejo nibe, ko ni fojuure wo olopaa yen, nitori pe igbagbo e ni pe olopaa yen ti gbowo. Bo se ri gan an niyen. Eni ti ko fun olopaa ni sile marun un ri lati ojo to ti dele aye, bi nkan ba sele sii, ti olopaa sise won gege bi ise, yoo so pe olopaa ti gbowo ni. Iru awon adojuko bee wa nile, to si po repete. Opolopo ejo ti won n mu wa ba olopaa lo pe ko soju olopaa. Sugbon ejo ti enikinni ro, ti enikeji naa so tie, ni olopaa maa sise le lori, to si gbe igbese, sugbon eni ti igbese yen ko ba ba laramu, oto ni nkan ti yoo maa so kaakiri.

AWIKONKO: Nje e ti e le so pato ise kan ti e se, to fee mi yin, tabi ti e le so fun wa pe e o le gbagbe?
OYEYEMI: Ise po ti a ti se seyin sugbon eyokan ti mi o le gbagbe, ti mo si maa n ranti daadaa, kii se pe bo ya inira kan wa lori ise yen, sugbon bi ise yen se gba lo je ki n maa ranti nigbagbogbo. Arakunrin kan lo fee soda titi lagbegbe Alapa ni Suurulere, nipinle Ekoo, bi moto kan se gba niyen. Eni to fi moto gba a yi lo wa gbe sinu moto bii pe o fee lo toju e, lo ba lo ju sibi kan, ibe ni eni yi ku si. Ko si seni to mo nomba moto yi nitori pe idaji ni, aaro kutu ni. Sugbon nigba ti mo maa debi ise lojo keji, won ti ko leta sile pe emi ni ki n lo se iwadi lori e. Mi o mo moto, mi o mo igba ti nnkan sele, mo waa bere sii ronu pe bawo ni mo se fee sise yi, ko si yori si rere, sugbon pelu ogo Olorun, Olorun fun mi se. mo se iwadi yen, mo pada ri eniyen mu, mo ri moto yen mu, ti mo si gbe eniyen lo si kootu. O je ise kan ti mo maa n ranti lore-koore.

AWIKONKO: Gege bi olopaa, nje ise kan wa ti e maa n fi ranti bi abamo pe ki lo mu mi se e?
OYEYEMI: Mi o figba kankan kabamo pe ki lo de ti mo fi sise yi ri, ise to wu mi lokan lati se nise olopaa. Mi o tii ba pade, mi o si ni ba a pade. Bi eeyan ba n sise kan, ti nkan to se die ba wa sele, to wa bere sii kabamo pe ki lo de toun fi se e, to ba je idi ise min in, nnkan to ju iyen lo le sele sii nibe. Ife okan se koko nidi ise teeyan ba yan laayo.

AWIKONKO: Opolopo igba ni won maa n so pe ofe ni beeli sugbon, sugbon nigba ti eeyan ba dele ejo, won maa n so pe ki won san owo beeli gege bi owo itanran. Ki le le ri so sii?
OYEYEMI: Beeli ile ejo yato si beeli ago olopaa, ko si nkan to kan olopaa ninu beeli ile ejo. Sugbon nkan ti a n pe ni beeli ago olopaa ni pe, ki eni ti won ba mu pe o se ese kan, ko wa eni to le duro fun un lai san owo kankan, nitori ti nkan ba tun sele lojo iwaju, eni yen ni won a lo o mu. Eni to ba lo san owo beeli, odaran loun gan an funra e, tori pe o fun olopaa lowo riba niyen. Eni to fun enikan lowo eyin ati eni to gba, odaran lawon mejeeji. Sugbon opolopo igba lawon eeyan wa kii farabale, awon gan an ni won a maa beere lowo awon olopaa pe ki lawon fee se, ti won a si maa fi owo lo awon olopaa pe kini kawon mu wa. Nigba ti olopaa naa ko go, oun naa a ni ki won lo mu egberun lona ogun naira wa. Mo n tenumo fawon eeyan wa pe ibikibi ti won ba lo, ti won ba n beere owo beeli lowo won, ki won pe ofiisi oluuleese olopaa lati fi ejo sun.

AWIKONKO: se ka so pe awon araalu lo n ti owo sawon olopaa?
OYEYEMI: Opolopo igba awon araalu lo n ti owo sawon olopaa lenu, nigba ti won ba n beere pe eelo ni kawon loo mu wa. Kini yi ti wa lokan awon eeyan wa ti won ba pe won pe ki won wa beeli eeyan won kan lago olopaa, igbagbo won ni pe owo ni won n beere, ti ko si ri bee. Awon ni won a maa beere pe eelo ni kawon mu dani tawon ba n bo. Ti awon gan an ko mo pe oran lawon n da, tori pe eni to fun un yan ni owo riba, ati eni to gba owo riba, odaran lawon mejeeji.

AWIKONKO: Ki wa ni ajosepo to wa laarin awon araalu ateyin olopaa?
OYEYEMI: Eto aabo kii se nkan ti olopaa nikan le da se, bi araalu ko ba fowosowopo pelu olopaa, olopaa ko le se nkankan. Tori e gan an la se ni igbimo kan ti a n pe ni Police Community Relations Committee, PCRC, awon ni won je gege bi ategun laarin araalu atawa olopaa, nitori pe ajosepo to manyan lori gbodo wa laarin wa pelu araalu. Bi araalu ba n fee to aabo to pe ye, won gbodo je ki ajosepo gidi wa laarin wa. Olopaa ko le wa nibi gbogbo nigba gbogbo lai kii se Olorun. Ise araalu ni lati pe olopaa, ki won si so pe awon ri oju kan to sajoji, tabi apejo kan to sajeji si won ladugbo won, sugbon ti ko ba si ajosepo kankan laarin won, bawo ni won se fee pe olopaa, tani won fe e pe. Ti won ba si pe wa, awa ko le mo nkan to n sele ni adugbo won. sugbon ti a ba tete gbo, a maa sare lo sibe lati lo wo nkan to n sele, ti a ba si rii pe apejo won lodi sofin, dandan ni ki a fi ofin gbe won, ki a si pe won lejo, ki o too di pe won lo huwa odaran to maa ta ba araale ati ara-oko.

AWIKONKO: Opo awon kan wa to je pe won o mo owo mo ese ninu esun ti won ba fi kan won, gege bi won se maa n so pe oriyeye niimogun?
OYEYEMI: Ko si eni ti olopaa le mu pe o daran, to maa so pe beeni. Gbogbo eni ti e ba mu, dandan ni ki won so pe awon ko mowo, awon ko mo nkankan nipa e, sugbon pelu iwadii to muna doko, opolopo ninu awon ti won so awon ko mo nkankan yi lo je pe leyin iwadi, la maa too sese mo pe awon gana an ni igileyin ogba, awon ni olori ninu iwa ibaje. Laipe yi la safihan awon odaran kan lojo die seyin to je pe okan ninu awon odaran yi, ibon ti won lo taa gba lowo, lo so pe ohun ko mo nkan ti a so, ohun ko ri ibon ri lati ojo ti won ti bi oun, sugbon leyin ose meji, awon akegbe e ti won jo huwa buruku yi, awon ni won loo ja moto gba lowo oga agba ileeko fasiti Crawford. Igba taa ri awon yooku mu, a tun pe awon oniroyin pe ki won wa a wo won, funra awon oniroyin gan an ni won ri ti won si daamo pe won ti muu ri, to si so pe oun ko mo nkankan, lo sese wa so pe igba ti won ko tii ri awon toku mu lo je koun so bee. Igba yen la sese mo pe oun lo wa moto ti won lo fi dena de okunrin yen, ti won si ja moto owo e gba. Oun ni olori won to n pese ibon fun won. eyi lo fa to fi je pe ko seni ti won le mu, to le so pe looto loun se e. Eni ti a ba si mu, leyin iwadii ti a rii pe ko ni nkankan an se pelu iwa odaran, dandan ni ka fi sile ko maa lo.

AWIKONKO: Bawo le maa n se awon iwadii yin?
OYEYEMI: Ise iwadii pin si orisirisi ona, o po repete. Bi iwa odaran ba se waye, bee na ni olopaa yoo se sewadi e. awon ise iwadi kan wa to je pe ero igbalode, iyen tekinologi (technology) la maa n fi se e. awon kan wa to je pe o gba ka gbera lati ilu kan lo sibo min in. awon kan wa to je pe o gba ki a lo foro wanilewo lenu awon to wa ni agbegbe yen. Orisirisi iwadii lo wa. Awon idawii kan wa to je ileewosan la maa ti lo se e, ki a too le mo okodoro oro. Fun apeere, eni ti won pa, bo ya won fun loogun je ni, lara awon iwadii bee ni ki won gbe iru eni bee lo sile iwosan, ki won yee wo, iyen toloyinbo n pe ni autopsy ti won si le fidi okodoro mule pe oogun lo gbe je to fi ku. To ba ri bee, a tun sese wa bere iwadii pe odo talo ti jeun gbeyin, iru ounje wo lo je, to ba seese ti a ri ajeku iru ounje bee, a maa le gbe ajeku ounje naa lo fun ayewo boya ounje naa ni.

AWIKONKO: Nibo ni ise eto aabo de duro
OYEYEMI: Ti e ba wo ipinle Ogun ni nnkan bi odun meji si meta seyin, e o rii pe adinku wa lori iwa odaran repete, a ni nnkan taa fi n ye e wo, ti a n pe ni crime statistics ti ma fi n se akosile bi iwa odaran se n lo. Eyi lo maa n je ka mo bi iwa odaran se po to laarin ilu lodun kan.

AWIKONKO: Nje e ti e le fi ise le omo bibi inu yin lowo?                 
OYEYEMI: Ko si nkan to buru nibe, to ba ti wuu lokan lati se. a le fi tipa mu esin de odo, sugbon a o le tipa fun un lomi mu. Ko si nkan to di mi lowo lati da omo to ba wu lati sise olopaa duro. Ise yi naa ni mo n se, oun naa si ni mo fi n toju e.

AWIKONKO: Nje o dara ki olopaa se oselu?
OYEYEMI: Ko si nkan to buru lati se oselu, sugbon olopaa to ba fe se oselu gbodo bo aso olopaa sile, ko si loo se e. ijoba to ba ti wa lori aleefa ni ti wa. Agbofinro la wa, a kii se oloselu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI