Owo olopaa ti te awon adigunjale to pa osise banki n’Ifo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 13, 2017

Owo olopaa ti te awon adigunjale to pa osise banki n’Ifo

Owo olopaa ipinle Ogun ti te awon adigunjale mesan ti won seku pa osise banki kan, Ogbeni Awodiran Sunday, eni odun mejidinlogoji lojo kerinla osu karun odun yi lagbegbe Lambe, Abule Alausa nijoba ibile Ifo, ipinle naa.

Awon odaran naa
Gege bi AWIKONKO se gbo, Lukman Taiwo, eni ogbon odun; Taiwo Babalola, eni odun mokandinlogbon; David Gbenga, eni odun marundinlogbon; Wasiu Olaegbe, eni odun merinlelogun; Ojo Aliu, ogbon odun; Taofik Sulaimon, eni odun merinlologun; Jamiu Taiwo, eni odun mokanlelogbon ati Igwe Ofosile ni won dena de Sunday ni nnkan bi aago mewa ku iseju meedogun ale ojo naa.

Gbogbo owo owo e, iyen egberun lona igba (N200,000) naira pelu opolopo kaadi ti won fi n gbowo, ATM to wa lowo e.

Kii se Sunday lo ni awon kaadi ATM yi, sugbon ileese banki to n ba sise ni won ko o fun un lati fi wa awon onibara wa si banki naa, ki oun naa si le gba ipin ti e leyin to ba ti ri awon eeyan, gege bi adehun to wa laarin oun ati banki naa.

Sugbon bo se n bo nile ni won lawon eeyan yi loo dena de e, ti won si gba gbogbo eru owo e lale ojo naa. Ohun ti a gbo ni pe Sunday bawon odaran yi sagidi pupo ki won baa ri owo owo e gba, sugbon omi po ju oka lo lo je ki won seku pa a.

Kii se pe awon eeyan yi deede seku pa, sugbon ki asiri won ma baa tu sita nitori ti won so pe Sunday da gbogbo won mo, ati pe adugbo kan an naa ni won jo n gbe lo je ki won pa a.

Bisele naa se waye lawon ebi Sunday ti lo o fejo sun awon olopaa Ekun Ajuwon, ti DPO Ogbeni Kazeem Afolabi si ti foro naa to komisana won, Ahmed Iliyasu leti, latigba naa ni won ti ran awon otelemuye sita lati mu awon odaran yi.

Gege bi Alukoro olopaa se foro naa to AWIKONKO leti nirole oni Tusde, o ni aipe yi lowo ba won, ti gbogbo won si ti jewo pe looto lawon gba owo lowo Sunday, sugbon nnkan to je kawon pa a ni pe o da awon mo, ki asiri ma baa tu lawon se gbemi e lojo naa.

Ni bayii towo ti te won, ti won si ti ko won de ogba olopaa to wa ni Eleweran, Abeokuta, Komisana Olopaa, Iliyasu ti pase pe kawon olopaa esin o koku FSARS ko won lo si ofiisi won lati lo tesiwaju ninu iwadii.

Iliyasu wa gbawon araalu lamoran pe ki won tubo maa je kawon olopaa mo nnkan to n lo nipa awon odaran ladugbo won. o ni ki won ma se bo enu won lati fi odaran han sawon olopaa nitori pe awon lo n ba ilu je.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI