Social Media n pa awa osere tiata lara pupo – Dele Odule - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 5, 2017

Social Media n pa awa osere tiata lara pupo – Dele Odule

Omoba Dele Odule to je gbajumo agba osere tiata lorileede Naijiria ti so pe oun ko si lori ero ayelujara social media nitori pe isekuse lo po nibe ati pe ayederu lawon nkan ti won n ko sibe.

Omoba Dele Odule
Dele Odule soro yi lakoko to n bawon eeyan soro nibi ale awon osere ti egbe osere TAMPAN se fun oloogbe Pasito Ajidara ni gbagede Asa Cultural Centre to wa ni Kuto nilu Abeokuta.

O ni ero ayelujara n se akoba to po fawon lori awon ayederu iroyin ti won n gbe jade sita, o leyi ko je kawon ni asiri tawon fi n pamo mo. O so pe bi won ba ri awon pelu enikan, oto ni nkan ti won maa ka a si fawon.

Odule so pe edun okan ati ibanuje lo maa n je foun nigba toun ba n ka awon nkan ti won ko sibe to si je pe kii se ooto. O ni social media ti so opo eeyan di oniroyin eke to je pe bi won ba gbo nkan kekere, lesekese ni won a fi ti won kun, ti won a si sare gbe sori ero ayelujara fawon eeyan lati ka.

O ni bi onikaluku won ba se n ri, ni won a maa se eda e, ti won a si maa fi ti won kun lorisirisi.

Nigba to n soro lori iku Moji Olaiya, Pasito Ajidara ati Olumide bakare, o ni kii se idunnu awon lati padanu ara awon, sugbon onikaluku lo ni akoko to maa lo laye, o kan je pe gbajumo tawon je nipa ise ti a n se lo je kawon eeyan maa ro o pe se lawon n pa ara awon.

O so pe ojoojumo lawon eeyan n ku nile aye, bo tile je pe awon to ba kan lo maa mo, ati pe osere tiata tawon je lo je ki okiki iku won maa kan kaakiri agbaye. O ni ko lonka lawon telo, kafinta, osise ijoba to n ku lojumo, sugbon nitori pe won kii se ilumooka tabi gbajumo bii ti won ni ko je ko bo sita.

Omoba Odule tesiwaju pe ko seni to koja iku, awon ti padanu awon eeyan bii Baba Ogungbe, Hammed Alaasari atawon mi in. O ni nkan to maa n ka oun lara ju ni bawon kan se maa n sare pe bi won ba gbo iku okan lara won pe kawon lo gba aawe olojo meje, olosu kan ati beebeelo, o ni iro lo wa nibe nitori pe won o mo pe eni ti won ni ko lo gba awe olojo meje sese pari aawe olojo mokanlelogun ni.

O ni ki lo de to je pe igba tawon eeyan ba ku lawon sese maa ri iran eke sawon pe kawon lo o gba aawe, ki lo de to je pe ti won ba ri nkan buruku sawon, won ko le bawon gbadura, ki won ye e fiku deru ba awon, bo tile je pe oun ti koja eni ti won le maa foro iku deru ba, nitori pe oun kii somode mo.

Omoba Dele Odule ni omodun mejilelogoji niya oun ku, oun si ti ju aadota odun lo. O leni to ba ri irikuri sawon, ko bawon be Olorun, ki won si bawon fadura jagun, ki won yee foro iku deru ba awon mo.

O wa gbawon eeyan lamoran paapaa awon osere tiata pe ki won yee deru ba ara won mo nitori pe ohun to ba maa sele ko le sai ma sele, ki won ma si baraje bi won ba gbo iru iroyin bee, ki won gba pe olojo onitohun lo de, gbogbo eeyan lo si dagbada iku.

Bee lo tun gbadura pe lagbara Olorun, awon ko nii kuku owowo, Olorun oke a daabo e bo gbogbo won atawon ololufe won. AWIKONKO naa wa gba a ladura pe ki Olorun tubo loora emi awon osere, awon amuludun atawon akoroyin kaakiri agbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI